Remmy Hazzan |
Onarebu Remmy Hazzan, to ti figba kan je igbakeji olori nile
igbimo asofin, to tun je omo egbe ile igbimo naa leemeji la gbo pe o ti gbase
tuntun gege bii agbenuso fun oludije ipo gomina labe egbe oselu APC iyen Dapo
Abiodun.
Ninu atejade kan ti Onarebu Tunde Okadunjoye to je akowe
ipolongo igbimo fidihe fegbe oselu APC nipinle Ogun fi sita lojo Aiku, Sannde,
lo ti salaye yiyan ti won yan an gege iriri e nidi oselu.
Gege bo se wi ninu atejade naa, lo ti so pe ‘ Bi ipolongo Dapo
Abiodun se n te siwaju, a fi akoko yii so feyin oniroyin atawon araalu Onarebu
Remmy Hazzan ni a yan gege bi agbenuso fun oludije gomina labe egbe oselu APC,
eyi to si ti bere ise e ni kiakia.
O so pe Okunrin ti won yan naa lo dije dupo ni ekun Odogbolu
sile igbimo asofin nipinle Ogun to si wole
nibe naa lo ti di igbakeji olori ile igbimo asofin laarin odun 2007. Ti
won si tun pada dibo yan an wole lodun 2011, Ojise Olorun ni nijo Ridiimu koda
lati odun 2000 lo ti je pasito ninu ijo naa.
.
Nigba to n gbase tuntun naa, Hazzan oun setan lati sise ti won
gbe foun yii, lati fi sin egbe ati lati sa ipa oun nipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment