Seyi Crown, Dupe J aiyesinmi ati Kehinde Soaga |
Iwode yii ti Agbejoro Tunji Bamisigbin ati
Ogbeni Kehinde Soaga sagbekale e yii ni won ti ko awon osere jo jakejado orileede yii lati lawon araalu loye nipa bi won se le dibo feni ti okan won n fe.
Bee ni won
tun lo iwode naa lati kilo fawon araalu lati ma se je ki ija waye lakooko ibo
naa ati pe eto won ni lati dibo feni ti okan won ba n fe.
Odunlade Adekola ati Musiliu Dasofunjo |
Iwode ti won
bere lati ofiisi Kehinde Soaga to wa ni Iyana mosuari lo gbe won de Sapon,
Itoku titi se ori omi ni Sokori nibi tawon osere naa ti n bawon eeyan soro,
lori ibo naa lona ti ko nii mu modaru daru.
Bakan naa ni
iwode naa tun gbe won de Ibara, OPIC , Kuto ti won si fabo e pada si ofiisi
okunrin naa pada, akoko ree ti awon egbe osere omo bibi ipinle Ogun yoo gbe iru
eto bee sile fun ilaniloye awon araalu fun ibo.
Saka, Taiwo Adeoluwa, akowe ijoba ipinle Ogun ati Eleso |
Lakooko ti
iwode naa n lo lowo ni won salabapade akowe ijoba ipinle Ogun iyen Agbejoro
Taiwo Adeoluwa toun loo sibi ipolongo oga e, iyen Gomina Ibikunle Amosun.
Bo se ri won
lo duro, to si gboriyin fun won fun eto nla ti won se lojo naa, o ni bo tile je
pe won ko fi tegbe oselu kankan se, o ni inu oun dun pupo pe awon osere naa le
seto to larinrin.
Oba Omilani |
Nibi tinu e
de, se lo fi akoko e sile die lati bawon osere naa ko wo rin fun iwode
ilaniloye naa ti won se. Nigba to n ba oniroyin wa soro lori agbekale eto naa,
Ogbeni Kehinde Soaga to sagbateru e so pe awon se eleyii lati fi le tawon
araalu ji fun ibo naa ati pe awon ko fi tegbe oselu se.
O so pe boun
se ronu agbekale eto ohun loun pe Tunji Bamisigbin ti won jo se ko kari e, o ni
ki i se eleyi nikan lawon ni lokan lati se ki ibo to bere sugbon awon muu
nikookan ni.
Lara awon osere tiata to wa nibe |
Bee lo tun so pe bawon osere tiata se wa nibe
lojo naa bee naa lawon olorin naa wa nibe lati jo fowosowopo saseyori eto naa.
Moto nla tawon osere naa wa ninu e |
No comments:
Post a Comment