Mo fee ki idagbasoke tun bo ba awon eeyan mi ni Yewa South, Ipokia- Biyi Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 11 January 2019

Mo fee ki idagbasoke tun bo ba awon eeyan mi ni Yewa South, Ipokia- Biyi Otegbeye

 Bi won ba n so okan lara eleyinju aanu, to ti n saanu fawon eeyan, paapaa awon eeyan e lati Yewa, Agbejoro Biyi Otegbeye ko pe meji, awon eeyan si mon on daadaa, ti won si tun kan sara si pe akoni okunrin.


Laipe yii ni okunrin naa jade lati dije fun ipo asoju-sofin niluu Abuja fun ekun Yewa South, Ipokia labe egbe oselu APC ninu ibo to n bo losu yii.

Okunrin naa ti ba oniroyin wa soro nipa erongba e lati dije, ati nnkan to ni lokan fawon eeyan to ba wole gege bi asoju-sofin niluu Abuja, ohun to ba wa so niyi.

Oruko mi ni Agbejoro Biyi Otegbeye, emi ni oludije fun ipo asoju-sofin fun ekun Yewa South, Ipokia niluu Abuja labe egbe oselu APC nipinle Ogun.

Ohun ti mo ni fawon eeyan mi ti won ba dibo yan mi wole

Adupe lowo Olorun pe o ti lo mi latii ran opololopo awon eeyan mi lowo lati nnkan bi ogbon odun seyin. Mo je oga agba fun ileese adojutofo kaakiri ile Naijiria, mo si ni anfaani lati bi odun mewaa seyin lati da ileese alaanu kan iyen NGO sil ta pe ni ipile anfaani ojo iwaju.Eyi yo je pe a ti lo lati fi ran opolopo lowo ninu okoowo fawon obinrin, a ti wa ise fawon odo, atawon osise feyinti.
Bakan naa nipa eto ilera, a gbe  eto wa kaakiri gbogbo Ogun West, eyi ti a ti n se lati bi odun mewaa seyin,ti a si tun se lowo. Eleyii lo wa ta wa ji lati wa sinu oselu. 

Gege bi amofin, mo nigbagbo pelu oore ofe ti Olorun fun mi lati gbe agbegbe ti  mo fee lo soju fun niluu Abuja laruge, lati rii pe awon odo wa rise to dara, lati tun ripa to laami ninu idagbasoke ati inawo ijoba apaponi  adugbo wa nibi.

Bee lo tun je mi logun awon eeyan wa je anfaani oro pupo ti o wa ni adugbo wa gege bi agbegbe to paala iyen border. Gbogbo awon nnkan wonyii, la ni lokan ta maa so awon aba yen di ofin to maa ran awon eeyan wa lowo lagba Olorun.

Ohun ti mo fee se to maa yato sawon to ti soju wa

Bi a ba n soro idagbasoke, oba mewaa igba mewaa ni, gbogbo awon asaaju wa to ti lo sofin,won se gudugudu meje, gege bi Olorun se fun won ni oore ofe, sugbon ebun ti Olorun fun onikaluku o yato, emi  je enikan to je pe lati kekere ni mo ti jafafa ninu eto oro aje, eyi tawon oloyinbo pe ni Commercr and Enterpreniumship, bakan naa ni mo tun je amofin, ti mo tun je eni to tun da ileese sile niluu yii ati ni Oke- okun.

Gbogbo awon nnkan ti eeyan dagba si ninu e yii, leeyan maa n ko da ni lati loo fi sise nile igbimo asoju sofin,o da mi loju pe ise temi ni lati yato gedeegbe si awon to ti wa tele, nitori anfaani tii onikaluku ni ko to depo otooto. Ni asiko ti wa, a gba pe igbe aye wa ni lati dara, a si tun gba pe gbogbo ona ti won fi dun wa lori awon eto wa, la maa di patapata, lati rii pe gbogbo nnkan to ba je eto fun Yewa Awori ati awon eeyan wa ni Yewa South ati Ipokia lati rii pe iderun wa fun tile toko.


Eto abo fawon eeyan mi je logun pupo

  Gbogbo wa la mo pe oro ijoba pin si ona meta,  ipo awon to ga ju wa, bee ni ipo awon amofin, bee la tun awon to n mojuto idajo wa lati rii pe ohun gbogbo lo bo se to, ati bo se ye.
Se e ri awon meteeta yii, won sise po fun rere ni sugbon ni abe ofin wa, won ti pin ise yen debi pe okan ko fara kan ara won, ipa kin in ni, a ran ipa keji lowo lati rii pe o mojuto ise e. ni abe ofin wa, eto abo je eyi to se pataki, labe ijoba apapo, gege bi asofin, ise wa ni lati rii pe awon to wa ni oke sise won doju ami gege bo se ye ki won se.

Ni adugbo wa nibi, ki i se oro Fulani nikan lo je logun nipa ti abo, won pa awon omo wa bi adie ni ni Border. Paapaa lori oro awon asobode, ati ija awon odo wa pelu awon asobode, ti won laagun lati ri pe ounje oojo won de, o si de odo awon ebi won, a ti ri opolopo to je pe won n sise won lona ti ko tako ofin sugbon to je rogbodiyan awon eeyan won pelu awon asobode, won ti gba emi opolopo. Gbogbo awon nnkan wonyii lo tako ofin.

Oro Fulani ti won n pa awon eeyan wa ti won n da oko won ru, gbogbo eeyan kaakiri orileede wa ni won ti bu enu ate lu pe ko bojumu. Mo si mo pe egbe APC  n ja raburabu lati rii pe awon iwa ibaje yii dekun.

Mo dupe pe mo wa ninu egbe APC, egbe ti ko gba iwa janduku bee laaye.Ise ti wa ni lati rii pe a tunbo fowosowopo pelu ijoba lati fopin si iwa buruku yii laduugbo wa.

Emi gege bi enikan atawon kan ti n sise lori gbogbo awon nnkan wonyii, ka ba mo gbogbo ibi to ti n sele, ka si la yekeyeke nnkan to n sokunfa won.


A mo pe ijobaipinle yii ti gbe igbese lorisiirisii, ti won ti gbe igbimo to n wo iru nnkan be yen,Ohun ta wa maa se ni pe ka gba gbogbo abajade ise ti won ti se, eyi ti won ko ba tii se, kaa rii pe won se, ki gbogbo nnkan ko le wa letoleto, ni asiko ti lagbara Olorun ti a ba de Abuja, alaafia yoo joba ni gbogbo adugbo wa.

Olorun oba lo n gbe eda sipo

Gbogbo eeyan lo mo pe Olorun oba lo maa n gbe eda sipo, gege bi e se mo, asiko ni gbogbo nnkan, ni 2015 ti mo koko jade, Olorun so pe ko tii to akoko ni, awon musulumi maa n so pe Olorun ni kunfaya kun, oba to n so bee, to n je bee, awa eda gbiyanju ni, sugbon ni akoko, nipa oore ofe Olorun, mo dupe pe egbe ti mo wa lo wa nijoba.

Ni 2015, egbe SDP ni mo ba jade, a o rii pe egbe yen latigba ti won ti gbe kale nigba naa titi di akoko ibo, boya osu meta si merin, egbe yen ko ni akoko lati ta gbongbo eyi ti won fi le se ipolongo, egbe olorire.egbe gbogbo eeyan to n se akoso lati orile ede wa de ipinle wa nibi, egbe APC, mo nigbagbo pe pelu ise ribiribi ti egbe yii ti se nipinle yii ati nijoba apapo, ise ribiribi taa ti ri ni mimu aye derun, taa ti ri ni eto eko, taa ti ri ni ilera, gbogbo ise yen lo ti royin egbe yii gege bi egbe ti won le gbara le fojo iwaju. Egbe yen ni mo n ba jade, APC.

Mo nigbagbo pe pelu oruko gidi tegbe yii n gbe kaakiri ati oruko rere ti emi gan-an ni adugbo mi ati ipa ti mo ti ko nigbe aye awon odo, obinrin, agbe, oloja gbogbo won a ti wa leyin, pelu iranlowo won, ibo to n bo, o da mi loju pe egbe APC lo maa wole. Biyi Otegbeye lo maa wa niluu Abuja.

Oro nipa APC, APM

APM lara APC ni won ti jade,ija lode lorin dowe, akitiyan tie si ti n lo lowolowo lati rii pe gbogbo egbe papo soju kan pada, emi nigbagbo pe gbogbo awon to wa ni APM lo maa pada wale ki ojo ibo to de, won a si dibo APC.

Gbogbo awuyewuye to n lo, lori pamari lo ti bere,sugbon nigba ti egbe fa eeyan kan kale inu opolopo ti n ro, nigba ti won gbe APM jade, opo awon to wa nibe lo ti pada si APC, bee lopo si tun n bo, nitori oogun won wa ninu egbe APC,won ko si gbodo je ki oogun naa ko gbe danu lasan. Mo ti so saaju pe ibo to n bo APC lo maa bori, mi o si ni nnkankan so leyin e.

Amoran        

Mo fee kawon eeyan mi roo daadaa, ki won to dibo, ki won ma ta ibo won lopo, nitori ojo iwaju won lo je koko, eni to wole yoo lo odun merin, ko ma waa lo je nitori egberun kan si egberun meji ni won yoo fi lo ta ibo won nibi ti ko ye si. Ka ma baa wa ninu ebi ati iyan fodun merin, mo si tun maa gba awon eeyan wa nimoran ko ma si darudapo kankan ki ohun gbogbo loo bo se to ati bo se ye, ipinle Ogun wa yii a o rii pe lati nnkan bi odun mefa seyin lati n je anfaani abo ati alaafia, ki awon araalu je ko maa lo bee.

Ki gbogbo awon eeyan jade worowo, gbogbo awon ti ko tii gba PVC, ki won lo si woodu won, mo gbo pe INEC ti n pin kaakiri bayii, ki won lo gba, ki won si toju e daadaa. Gbogbo awon ti ko ti dibo ri tele, ki won jade lati wa dibo naa.

No comments:

Post a Comment

Pages