Osoosu ni mo fee maa mu inu awon ti mo fee lo soju fun l’ Abuja dun- Onimo- ero Lanre Edun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 11 January 2019

Osoosu ni mo fee maa mu inu awon ti mo fee lo soju fun l’ Abuja dun- Onimo- ero Lanre Edun.




Onimo- ero Lanre Edun ki i se omo kekere nidii oselu, o ti figba kan je alaga ijoba ibile Abeokuta South, tawon eeyan si kan sara si pe o se daadaa, o si se iwon to le se. Bakan naa oun tun ni oluranlowo Pataki fun Gomina Ibikunle Amosun, lori oro ayika.

Okunrin naa wa lara awon to jade lati dupo asoju-sofin fun agbegbe Abeokua South niluu Abuja labe egbe oselu APC. Lanre Edun ba oniroyin wa soro lori awon nnkan to fee se fawon araalu e, to ba depo naa. Ohun to so ree.

Idi ti mo fi jade dupo asoju-sofin lati soju agbegbe Abeokuta South

Ni akoko, mo dupe lowo Olorun, leekeji, mo dupe lowo gomina wa, Ibikunle Amosun, nitori okunrin takuntakun ni, eeyan to je pe o weyin wo,to si tun duro tan pe eni toun fee, ki won ba oun satileyin fun ni onimo ero, Lanre Edun.

Mo tun wa dupe lowo gbogbo omo egbe APC lapapo, ni pataki julo, gbogbo araalu patapata, nitori nigba to ye naa ni won pe mi, ti won so pe akoko Olorun lo ju, akoko e naa lo si de, mo wa dupe lowo won, fun pe won yan mi lati wa loo soju won nile igbimo asoju-sofin fun agbegbe Abeokuta South, to si je ijoba ibile to je premia ni Naijiria ni , ki I se eyi to se fowo ro seyin, ijoba ibile kan soso to ni nnkan ti won n pe ni gbongan Centinary, mo dupe lowo won.

Bi won ba si dibo yan mi wole tan lojo kerindinlogun, osu keji, odun taa wa ninu e yii, won a ri ohun ti awa naa maa gbe se, nitori kin ni, a ti se alaga ijoba ibile ri o, ileegbe igbalode ti mo se, to wa ni Kuto niluu Abeokuta yii, ko si meji e ni Naijiria.

Bi won ko ba si gbagbo, mo fee ki enikeni wa lati Naijiria yii, ko wa wo, iyen naa ni mo tun fee wa lo se lote yii, nnkan tawon kan ko ti se rii, ti won fi n lo, ni mo n bo waa se fun won, okunrin ni o, obinrin ni o, omode ni o, agbalagba ni o, onise owo ati beebee lo, ohun ti Olorun fi maa ran mi lowo, ti won maa fi ri nnkan ti enikan ko tii se fun won ni Abeokuta South, mo n be Olorun ko se fun mi.

Awon nnkan ti mo ni lokan lati se

Awon to ti n lo lati ibi, won maa n se etanje kan,won a ni won ni kawon loo sofin, sugbon afefe ti fe, a ti ri furo adie, ti a ba sofin, iyen ko ni ka maa soju aanu, oro oju aanu yen lemi fee  ni agbayanu ti won yoo fi maa so pe ha, awon ko mo pe bayii ni.

O dun mi pe awon Yoruba diedie, iranlowo ta n pe ni ironilagbara, awon ise akanse a je eyi ti mo maa fee se, nitori emi maa n feran lati se ipo kin in ni nnkan ti mo ba se, tawon eeyan maa roo pe se Abeokuta South ni won se eleyii si.

Gbogbo araalu patapata lati woodu meedogun ni Abeokuta South ni mo ti n be Olorun pe nnkan ti mo maa se lati fi je iranlowo fun won losoosu, mo maa se.

 Bi igboraye yoo se wa laarin emi atawon araalu.

Emi gege bi enikan, mi o fi bu enikeni o, ilu yii ni won bi mi si ti won si ti to mi dagba, a mo ara wa lotun, a mo ara wa losi, ko sibi temi fee sa si, nitori omo ilu ni mi. Mo si tun tun so ni osoosu, mi o fee so pe iye igba bayii sugbon ko ni ye, ki I si se eekan ni nnkan maa wale, ki i se eekan losu, nitori mi o tii mo bohun se ri.

Eto ni fawon odo.

Awon odo je mi logun pupo, mo fee je pe nnkan ti mo maa se fun won, won a le da duro, won a si le da gbe odo egbe e bii merin marun un dide. Fun apeere, nigba ti mo je alaga ijoba ibile Abeokuta South, won ni won ki I se eto ogbin, emi gbe e dide, mo si fi pawo wole fun ijoba ibile. Iru e naa ni mo maa se, amo sa, mo maa fee ki n se kan ti won yoo fi kan sara, ti akoko ba to.

Nipa kaadi idibo

Erin pa mi, o da kawon eeyan ba n ra kaadi idibo, ko si tun da, nitori pe niluu ti a wa wa yii, ilu olaju ni, gbogbo araalu mo mo won, won a fee fi ko elomii-in logbon lati je ki won mo pe won laju.
Ohun ti won a se ni pe won yoo gbowo sugbon ibi ti okan won ba ni ki won dibo si ni won yoo dibo si, ki I se nitori owo ti won fun won yen, won mo pea won to n fawon lowo yen, jibiti ti won ti lu araalu seyin, owo e ni won n da pada.

Mi o rawon taa jo n dupo gege bi eru.

Bi won ba so pe o kaju e, omo Edun lo n je bee o, nnkan to de, lode ni o, idi ni pe se e mo pe eeyan ni oga, to je pe leseese ni nnkan se, lojo kan in ni ana, lodun 2007, emi Olanrewaju Edun yii naa ni, taa dije, a a wole, won si se, bo se wu won.

A n se ejo naa, o loo daadaa, o ku ojo marun un, ti idajo maa waye, lomo ilu Egba je olori ile igbimo asoju-sofin niluu Abuja, won ba ni omo Egba lo sese kuro gege bi olori ilu, awon naa lo tun se ipo kerin, won ni ka fi sile fun, sugbon ife ilu taa ni ati ti oga wa, a fi sile fun un.

Lodun 2011, ni Segun Williams de be, won lomo egbe awon ni, bi won se bebe to pe ki won fun mi, la ba fi sile fun un, o se odun merin, o tun fee se merin mii in, olori wa, iyen gomina ni ka fi sile fun un, a tun gba, o ti se odun mejo. Temi ti wa fee di odun merindinlogun bayii, oun tun wa so pe oun fee lo eleeketa, yiyo ekun tojo ko, emi ati e jo wa lenu e ni.

Sebi a jo se pamari ni, ninu pamari, a mo ibo to ni, o wa loun fee jade loo fegbe kan, mi o ni dan nu, a fi gbogbo e le araalu lowo.
  
 Amoran mi

Amoran mi fawon ara mi  Abeokuta South ni pe ki won jade lojo idibo ki won dibo awon fun Aare Mohammadu Buhari gege bi Aare, Gomina Ibikunle Amosun gege bi Seneto ati emi omo won Lanre Edun fun asoju won nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja

No comments:

Post a Comment

Pages