Nitori wahala oro oselu to n sele
nipinle Ogun, paapaa eyi to waye lojo Abameta, Satide to koja yii niluu
Odogbolu nibi tawon toogi kan ti yinbon fi koju awon alatileyin egbe oselu APC,
oludije gomina labe egbe oselu APC, Omooba Dapo Abiodun ti so pe ipinnu oun
lati di gomina ki i se lati ta eje enikankan sile nipinle naa.
Ninu atejade ti Onarebu Remmy Hazzan, to je agbenuso fun okunrin naa
fi sita lonii in, ojo Aje, Monde, lo ti so pe ipinnu oun lati dije fun gomina
ni lati bori ati lati sin awon eeyan, oun ko si ni fe ki enikeni ku tabi farapa
nitori ti won satileyin foun ati egbe.
Gege bi atejade naa se wi, lo tun ti
salaye pe oun fise toun se nile yii ati ni oke okun sile lati sin awon eeyan
ipinle Ogun, ti mo si ni ifokanbale lee lori O
ni oun si ni ajosepo pelu awon eeyan lagbaye lati fi ran awon osise
atawon eeyan lowo, oun ko fee ki won pa enikeni tabi se won nijanba, o loun ko
fee se gomina lori awon ti olori ebi won ti ku tabi so di alaabo ara nipase
wahala oselu.
O wa mu oro kan ti ajo agbaye nipa
eto omoniyan so jade lodun1948, O ni erongba awon eeyan gbodo je nipa tijobam
irufe e si gbodo waye nipase ijoba tiwa-n-tiwa, lati dibo ti ko nii mu wahala
tabi itajesile dani. Nitori idi eyi, o pe gbogbo awon oludije oloselu lati sise
labe ofin, ki won si maa gbagbe pe omo iya kan naa ni gbogbo wa, wahala ko ki i
bimo re.
O ni nnkan ti ipolongo ibo gbodo wa
fun ni ko ma si ijangbon, iyen si ni idaniloju tawon se latile, ko si wa ye ki
won wa da gbogbo e ru bayii.
Ni ipari oro e lo ti ran awon araalu
leti nipa kaadi idibo won iyenPVC, o ni ti won ba ti gba, ki won toju e daadaa,
oun ni yoo si fun laye gege bi oludibo.
O ni ki won ma se ta ibo won, eto won ni. *
No comments:
Post a Comment