![]() |
Tunde Oladunjoye |
Egbe oselu APC nipinle Ogun ti ke si oga olopaa patapata lorileede yii, Ibrahim Idris, lati se iwadii awon ti won n da wahala oselu sile nipinle Ogun lenu ojo meta yii.
Ninu atejade kan ti Ogbeni Tunde
Oladunjoye, to je adele akowe olupolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun gbe jade,
lo ti so pe bawon toogi oloselu se n da wahala sile lenu ojo meta yii n ko awon
lominu.
Ni nnkan bi ojo meloo kan seyin ni
won lawon toogi loo da ibi ti Omooba Rotimi Paseda to je oludije gomina labe
egbe oselu SDP ti n se ipolongo e niluu
Ijebu- Ode.
Won ni ko tii pe wakati merinlelogun
ti iru nnkan bee sele, ti won fi loo da ibi ti Dapo Abiodun, oludije gomina
labe egbe oselu APC ru, lakooko tawon alatileyin e n duro de e iyen lojo
Abameta, Satide, ose to koja..
Oladunjoye tun so ninu atejade naa pe se lawon toogi ti
won ko mo naa dana ibon bo awon eeyan nibi tawon meta ti farapa, ti olopaa si
wa ninu won.
O so pe awon ti figba ke gbajare
sita pe awon kan gbimo lati maa da wahala sile lasiko ti oludije gomina won ba
bere ipolongo, iru e lo so pe o ti n sele bayii.
O wa ke si oga olopaa patapata
lorileede yii lati gbe igbimo olominira kan dide ti yoo se iwadii lori awon
isele to n waye naa, ki won si fawon to ba jebi jofin.
O wa mu da awon alatileyin egbe
oselu APC loju pe awon yoo maa tesiwaju ipolongo woodu si woodu tawon se laisi
wahala, tawon yoo si ri pe abo to daju wa lori won ati dukia. O wa ke si awon
olopaa lati sise won gege bi ofin se la sile fun won, ki won ma si segbe leyin enikankan.
No comments:
Post a Comment