Sina Kawonise |
Okan lara awon oludije fun ipo gomina nipinle Ogun ni Ogbeni Sina Kawonise, tawon kan tun pe ni SK, abe egbe oselu YES ni okunrin naa ti jade, tawon eeyan si n fun un ni atileyin.
Laipe yii ni okunrin
naa ba oniroyin wa soro lori erongba e lati di gomina nipinle naa.Ohun to ba wa
so niyii.
Idi ti mo fi kuro ninu egbe oselu SDP
loo dije ni YES
E e maa seun
gan-an ni, bee ni awa la gbe oro SDP kale, nigba taa kuro nijoba Afenifere, la
loo da SDP sile, la loo foruko e sile, a kowo sile, lati foruko egbe naa sile,
ohun to maa yato sohun tawon egbe yooku n se, oro owo, oro a-lu-koro-fowo-yi, ki
a maa gbe are, felebi, ki a maa gbe ebi. falare, nitori e la se gbe egbe SDP
sile, nigba ti a si fee dije, egbe to je pe awa la a gbe sile, to ni awon nnkan ta a so, nipa oro omoluabi
ti a ro pee egbe naa wa fun, sugbon nigba ti a bere, gbogbo awon nnkan ti a n
sa fuun n APC, PDP, oro owo, jagidijagan, toogi, nnkan ti won ko wa sibe niyen,
ti a fi kuro nibe.
Baba mi to
ti file aye sile, Olorun ko fi orun ke, o soro kan pe to ba wa nile ti won ti n
ta tete, o ni to ba je pe iwo lonile ko le won jade, to ba si je pe awon
lonile, ko jade fun won, nigba ta si ri nnkan ti won so SDP da, e o ri pe ni
apapo egbe naa gan-an, won ko niyanju, gbogbo e ri bo se ri.
Idi ta se ni
gege bi omoluabi, taa ri pe nnkan to le ko ba wa, la se kuro nibe, ti a ko fe
ariyanjiyan la se lo sinu egbe oselu YES, egbe ta a mo pe ko si isoro awon
oloselu kankan nibe, bi a se domo egbe niyen.
Igbagbo egbe oselu YES ninu ibo to n
bo lona.
Igbagbo ta a
ni ninu egbe naa ta pe Yes Electorate Solidiarity lo n je, nnkan to tumo si ni
pe gbogbo awon oludibo tawon oloselu wa n foju pare, ti won ka won kun, awon la
wa ko mora. Ohun ti mo n so ni pe awon oloselu ti won ko ara won sinu oselu mii
in, won ko to idamewa awon ta wa n ba soro lawon ti won ti foju pare, ti won ko
tun ka won kun, nitori pe awon eeyan
tuntun bee ti won ko nipa ninu oselu la le se, ni won le gbo nnkan taa n se,
nitori ara nni won, awon eeyan to n fee ayipada nitooto, ki i se awon
onijegudujera, awon taa n ba soro niyen.
Won si n gbo
nnkan taa n so, iyen nikan tun ko, awon
ta n ba soro yii, kii sawon to n beere owo lowo wa, ki won to le satileyin fun
wa.Oro ko tii to so bayii nigba ti esi
ibo ba jade, a maa mo nnkan taa n so. Nitori pe ariwo ko ni orin o.
Eto ti mo ni fawon araalu.
Eto ti mo ni
po o, bi won se n se ijoba tele, lakooko
yii paapaa ni pe lati oke wa si isale, awon adari wa ni won ro pe awon mo nnkan
ti araalu n fe, awon ni won mo nnkan taa nilo, emi ti mo wa lati Ijebu North,
ojo kan laa ji, ti won bere si nii se biriji nla si Ijebu Igbo, ibi to je pe ko
si sunkere fakere moto, nitori pe ona tawon fi n se tijoba, awon ni won kan maa
pinnu nnkan ti araalu n fe.
Kii se pe
won maa beere lowo araalu, kin ni nnkan ti won fe, a fee fopin si nnkan bee, a
fee da ijoba pada sodo awon araalu. A ni eto kan tawon oloyinbo n pe ni Ward
Development Council iyen idagbasoke agbegbe woodu. Nnkan taa fee se ni pe lara owo ti a n ri ti
won n pe ni IGR, a fee maa mu idameta wa ninu mewaa la fee ma san fawon woodu
to wa nipinle Ogun losoosu.Woodu kookan ninu igba, ogbon ati mefa to wa nipinle
yii, la maa pin fun won, won lo maa pinnu nnkan ti won fee fi se.
Awon ise ilu
ti won maa se, kii se pe a maa gbe fun alagbase ti yoo maa kowo araalu sapo,
awon funra won lo maa sise e, awon ara agbegbe yen lomaa fenu ko ti won yoo se
fun ara won.
Ohun ti mo n
so yii, o ti sele ri laye Awolowo, ijoba Bisi Onabanjo, tawon omo egbe UPN ba
fee gbe ise, won a gbe fawon omo egbe.Won maa n pin laarin ara won.
Awon owo
ribiribi ti won naa lori a tun ona se, awon araalu oyinbo lo n ko owo wa lo, awon
tiwa ko rise nibe.
Nipa oro ise
fawon eeyan wa to je pe ko si ise repete, a fee maa seto idawo fawon eeyan wa
to je pe awon onise-owo,awon to ti kose,ti owo je idiwo fun won, a maa ya won
ni owo. Nipase egbe alajeseku, ti won maa ri owo yen gba, ti won yoo si maa san
pada.
Lori eto
eko, a maa ri pe a ko je awon tisa lowo, esi idanwo WAEC odun to koja yii, ipo
kokandilogun nipinle Ogun wa lorileede yii.Ipinle wa to ti maa n wa nipo kin in
ni, ipo keji, ki lo si fa, inu awon oluko ko dun, won je won lowo repete, ti
won ko fun won. A maa rii pe a se.
Gbogbo yara
ikekoo ti won ti n sise la maa rii pe o dara, a o tun maa se idanilekoo fawon
oluko loorekoore, ti eko yoo tun fi lo soke, ati beebee lo.
Ayipada rere ti egbe YES fee mu ba
araalu.
Ohun naa ni
mo ti n salaye yii, ona ta fee mu ayipada rere bawon ni pe ka yo owo awon
oloselu, awon jegudujera kuro ninu nnkan to n sele yii, awon araalu la jo n se
ipolongo, ti won mu owo sile tawon naa mu owo sile lati fi jo maa se e.
Bi a ba
yowo awon oloselu yii kuro nibe nigba ti egbe won ba tin a milionu, milionu,
nigba ti won ba wa debe, owo yen ni won yoo ma wa ona lati da pada. A fee yowo
won kuro, ti a ba si maa sejoba, awon eeyan yii naa la maa gbe fun. Ayipada to
je toooto ti ki i se tenu lasan la fee se.Ohun tawon omo ipinle Ogun ti n foju
sona fun ni.
Nitori e la
se n dawo, ti ko si baba isale kankan, gbogbo awon yen si ree, won ko nifee
araalu, won fomo won sile, awon ti won fee maa dari won ni won maa n fi sibe
sugbon ti ko si ninu egbe oselu YES. Olorun
nikan la wa gboju le, oun ni baba isale ti wa.
Bi owo yoo se maa wole laini araalu lara
Lati
pawo wole, mo so fun yin pe a maa se
idagbasoke agbegbe woodu wa, awon bii kafinta, gbenagbena, birikila,eni to n yo
buloku ati beebee lo, won yoo ri se, nigba to ba ti ri be labe ijoba, eni to n
ya owo, to n san ida marun un ninu ogorun un losooso lori e. Nigba ti odun ba
pari awon naa yoo sanwo ori.
Tawon eeyan wa ba ri se latowo ijoba, awon naa a
san owo ori pada.
Nipase awon
eto ta a ni nile, aimoye awon omo ipinle Ogun ti won ko din ni milionu ti won
ko ri se tele ti won yoo maa sanwo ori nigba ti won ba ti nise lowo. Owo ori ta
a n so yii, laarin odun meji ti a ba debe, yoo lo ni ilopo lona meji.
Nipa ona
ipinle Ogun pelu Eko, nnkan ti ofin owo ori so nip e ibi ti a ba n gbe la maa
sanwo ori wa si. Eni to n gbe ni Ibafo to n sise ni Ikeja, ipinle Ogun lo ye ko
sanwo si, ki i se Eko to ti n sise. Gbogbo owo wa ti won n gbe lo si Eko la maa
gba pada. Eyi to se koko nibe ni pe tawon eeyan ba n ri je lowo ijoba, awon naa
yoo sanwo.
Bi aarin awa
ati osise yoo se gun rege
Se e ri awon
osise wa nipinle Ogun, won maa dara, omoluabi ni won, mo ti bawon sise ri nigba
ti mo je komisanna feto iroyin labe Otunba Gbenga Daniel, mo ri pe won je eni
to kun oju osuwon.
Owo ti won
gba losoosu yen, ohun to dara ni la ti san lakooko to ye, ki ibi ti won ti n
sise, ko dara. Nigba ti akoko igbega won ba to, e je ki won ri gba, ki ofiisi
won bojumu.Ka si rip e gbogbo nnkan ta ba n se, a n je ki won mo, ko ju bee lo.
Awon nnkan ta fee se niyen, to ba si to akoko ifeyinti,a maa ri pe won gba eto
won. Owo yii ko po, ko ye ka maa fi ni
Lori egberun lona ogbon naira afikun
owo awon osise
Se e ri bi a
ba n san egberun lona ogorun un naira gege bi afikun owo awon osise ko to jeun,
sugbon gbogbo wa ko mo bi apo ijoba se ri, iru awon nnkan bayii soro da si, bi
a ba wo akosile osuwon ijoba.
Awon ijoba
kan ti so pea won le san owo na, Eko lawon le se, bee lawon kan ni awon ko le
san, bigba ta ba wo eto isuna ipinle la to le so, sugbon loju temi, egberun
lona ogbon naira, ki i se nnkan to je babara.
Loooto emi ati Gbenga Daniel ko si
ninu egbe oselu kan naa sibe oga mi ni
Emi ati ati
Otunba Gbenga Daniel ko si ninu egbe oselu kan naa,oga mi ni won, gomina tele,
ko si awuyewuye kankan, oro oselu nikan la fi yato, awon wa ninu egbe atijo,
awa wa ni tuntun, nitori egbe ti won wa gbogbo wa la mo won, egbe PDP, ti won
mo si pinpin pinpin awa o si ninu egbe bee.
Sugbon oun
gege bi eleran ara, eeyan daadaa to si je omoluabi, bo se je niyen.
Ajo INEC
E je ka maa
wo nnkan ti ajo INEC fee se lori ibo to n bo lona yii, Ojogbon Yakubu to je oga
won, ibo gbogbogboo akoko to maa se ni eleyii, e je ka fun un laye. Won ti so
fun wa pe ibo to n bo yii, ko ni si modaru nibe. Adura ni ka maa fi ran won
lowo.
Awon oloselu to n fawon araalu lowo
lati dibo fun won.
Nnkan buruku
pata gbaa ni, nnkan ta n so fawon araalu naa niyen, dibo ko se obe, obe te e se
lati bi odun merin se oun naa le si n je di akoko yii. Owo buruku ni.
Owo ti won
tie n fawon eeyan wa naa, owo ebo ni, raisi ti won pin fun won, won ti fi se
saara, idanilekoo ta n so fawon eeyan wa niyen, e e ma gba owo ti won ji ku, ti
e ba ti gbowo, e tita kadara yin fodun merin.
Won ti mu da
wa loju pe enikeni to ba fawon lowo lati dibo, ota awon ni
No comments:
Post a Comment