Gongo so nibi ayeye isin idupe olodoodun ti Otunba Gbenga Daniel se ni Sagamu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 14 January 2019

Gongo so nibi ayeye isin idupe olodoodun ti Otunba Gbenga Daniel se ni Sagamu


Otunba Gbenga Daniel ati Iyawo e, Yeye Olufunke nibi ayeye isin idupe olodoodun naa

  Ese ko gbero lojo Aiku, Sannde,  niluu Sagamu nibi ayeye isin idupe olodoodun ti Otunba Gbenga Daniel, gomina tele nipinle Ogun, to tun je alakoso agba fun ipolongo ibo aare fun Abubakar Atiku maa n se, eleekerinla iru e.

Soosi Abraham's Tabernacle, ijo awon onitebomi iyen Baptist International to wa niluu Sagamu,  ni isin naa ti waye nibi topo awon oloselu lorileede yii ti won tun je omo egbe oselu PDP ti wa ba okunrin sajoyo idupe odun tuntun naa.

Bawon oloselu jakanjakan se wa nibe, lawon oba alaye naa wa nibe, Ooni tilu ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi naa ko gbeyin bee bi Akarigbo tile Remo lo saaju awon oba Remo wa, bakan naa lawon oba kan lati Ijebu naa wa nibe, to fi mo Olowu tilu Owu, Oba Adegboyega Dosunmu.

Oludije fun ipo aare labe egbe oselu PDP, Alaaji Atiku Abubakar ni alejo pataki lojo naa sugbon iyawo e, Oloye, Arabinrin Titi Atiku lo wa soju oko e nibi ayeye naa.

Ninu oro obinrin naa to so loruko oko e, lo tun ti so di mimo pe eto atunto toko oun seleri pe oun yoo se toun ba di aare orileede yii ninu ibo to n bo lojo kerindinlogun osu to n bo, ko yipada nitori gbogbo awon lawon mo pe atunto lo le mu ki ilosiwaju ba ile Naijiria.
Otunba Gbenga Daniel ati Ooni tilu Ile-Ife

O ni atunto yii bakan naa lo le mu isokan ba orileede wa, o ni oko oun ti setan lati je ki Naijiria sise pada, bee lo si tun ti pinnu lati gba awon eeyan kuro lowo iponju, osi ati ebi. O ni gbogbo nnkan to ba to to si ye awujo wa lo setan lati se.
 
O wa ro gbogbo awon omo orileede yii lati dide atileyin fun oko e lati depo aare nibi ibo to n bo naa. Bee lo ni ko ni doju ti won, nitori o ni akoko ti to kawon eeyan kuro ninu oko eru, o loko oun so pe oun yoo pese ise fawon odo ti ko nise lowo, ati pe gbogbo awon ohun amayederun ni yoo te awon lowo, toun ba fi le depo naa.

Nigba toun naa soro nibi ayeye naa, Otunba Gbenga Daniel sapejuwe Atiku gege bi eni ti Olorun fee lo lori atunto to ba di aare, to si le mu ileri e se.

O wa  ni Atiku ki i se eleyameya nipa oro elesin de, gbogbo esin lo nigbagbo ninu e, ti ko si fi kan se.

Ninu oro oniwaasu lojo naa, Eni owo, Dokita, Olanrewaju Aransiola ti ijo Gethsemane Prayer Ministry,  o so pe  nnkan to le ko wa yo ninu isoro ta n dojuko lakooko yii ni asaaju nireti to si tun fara jin.


No comments:

Post a Comment

Pages