Segun Sowumi |
Bi iroyin to n lo nigboro ilu Abeokuta nipa oludije fun ipo asoju-sofin niluu Abuja fekun Abeokuta South labe egbe oselu PDP, nipinle Ogun, Ogbeni Segun Sowumi, ba fi le je oooto, a je pe ki okunrin naa maa mura sile ni, nitori bi won se lawon eeyan se fi lokanbale pe ko ma beru nipa ibo ti won yoo di lojo kerindinlogun osu to n bo.
Gege bi
iwadii wa, gbogbo ibi ti okunrin naa de ni won ti n fi lokanbale pe ko sewu
loko, bee naa ni ko sewu nigboro, ohun lawon yoo dibo awon fun.
Won ni bo
tile je pe egbe oselu PDP lo ti jade, awon yoo satileyin fun un, nitori ibo
tawon fee di lote yii, ki i se ti egbe oselu bi ko se oruko.
A tun gbo pe
won ni ipa pataki ti okunrin naa ti ko lagbegbe to ti jade wa tun je nnkan to
tun ran an lowo, won lo yato sawon to ti wa nibe fodun mejo, to je awon ko ri
nnkan gidi ti won se, a fi awon ti won.
Bakan naa la
tun gbo pe gbogbo ona lawon alatileyin okunrin to tun je agbenuso fun Atiku
Abubakar nipa ipolongo ibo aare n sa lati rii pe won sise fun okunrin naa lati
wole ninu ibo to n bo naa.
Okan lara
awon eeyan naa to ba wa soro so pe ninu gbogbo awon oludije to jade lati dupo
asoju-sofin lagbegbe odo awon, Segun Sowumi nikan lawon mo pe o ka oju e,
nitori awon mo pe oloye, to si le farabale gbo nnkan tawon ba n so ni.
Idi niyii ti
won fi wa pariwo pe ki eni to ti lo odun mejo, to tun fee lo lo odun merin mii
in lo senpe, nitori oba kan ki i je kiluu ko fe.
No comments:
Post a Comment