Oku Sola |
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii
lowo, inu ibanuje lawon ebi omokunrin kan ti won pe oruko e ni Sola Odunaro wa
bayii, nitori bi won se ni won sa a ni ake pa lori ede aiyede ti won so pe o
waye pelu awon ore e lojo Isegun, Tusidee, ose yii.Ado- Odo nijoba ibile
Ado-Odo Ota nipinle Ogun nisele naa ti waye.
Gege bi a se gbo, Ni nnkan bii aago
mesan an ni ale ojo Aje, Monde ni won ni wahala be sile laarin Sola ati ore e
ti won n pe ni Azeez Gade, ti won si bere si nii soro buruku si ara won. Awon
to so boro naa se je salaye pe nibi tawon mejeeji ti n fa oro naa mo ara won
lowo ni enikan ti won n pe ni Tunde Killer ti de.
Sugbon kaka ko yanju oro naa laarin
won, se ni won lo tun ru sii to fi di pe awon mejeeji bere si nii na Sola, ti
won tun saa ni ake lairo gbogbo ebe ti won ni iya omo naa n be won lakooko ti
won fi na omo e ohun.
Kawon eeyan to dide lati la won, won
ni won tii sa Sola ni ake pa, loju ese lo si ti ku patapata, won ko si mo bi
Tunde ati Azeez ti won fura sii pe omo egbe okunkun ni won se salo.Ti won ko si
ti ri won titi di akoko yii.
Okan lara awon olopaa ti won pe
nigba tisele naa waye to ni ki won foruko bo oun lasiri jeri sii pe loooto
nisele naa waye, awon si ti n gbe igbese bawon yoo se fi to awon oga won leti
ni Eleweran niluu Abeokuta. O ni awon ti ngbe igbese lori bawon yoo se mu awon
odaran to saa lo naa.
No comments:
Post a Comment