Oloye Lekan Alabi laarin omo egbe ANTP ati TAMPAN lojo naa |
Ojo
Abameta, Satide, ose to koja yii legbe osere ANTP ti eka ipinle Oyo sayeye
alarinrin kan ni gbongan Cultural Centre to wa niluu Ibadan, bakan naa ni won
tun lo anfaani ojo naa lati fawon eeyan kan ni awoodu.
Ohun to je
ki ayeye ohun fi ya awon eeyan lenu ni bi won se ri awon omo egbe osere TAMPAN,
eyi ti Sokoti saaju won wa bawon egbe naa sajoyo.
Idi ni pe
lati nnkan bi odun meta seyin ti wahala ti wa ninu egbe osere ANTP tawon kan fi
yapa loo da egbe TAMPAN sile ni ko ti ajosepo to danmoran laarin won, debi pe
won ki i pe ara won sise, nibi to le de ka ni won n ka ara won mo koro ni, won
yoo maa gba ara lese daadaa, nibi ti ija naa buru de.
Sokoti ati Jimoh Aliu |
Sugbon
laipe yii ni ija naa pari, bo tile je pe a tun gbo labele pe ko tii pari tan patapata,
enu aye ni won n saa fun laarin ara won. Won ni aimoye igba ni Jimoh Aliu naa
ti loo sibi ayeye TAMPAN, lati le je ki irepo fi wa.
Bi Sokoti
tun se wa saaju awon eeyan e wa sibi ayeye ANTP niluu Ibadan ti fihan pe ife ti
won fee ko joba laarin won ti pada. Eyi lo mu inu Oloye Lekan Alabi, okan lara
awon to gba awoodu lojo naa dun pe se pe awon mejeeji si tun le bara won se po.
O wa lo
akoko naa lati bawon soro ki won je ki gbogbo nnkan to ti sele seyin ko di afi
seyin ti eegun fi aso, ki won si maa bara won se gege bi tomotiya.
Lara awon to da awon eeyan lara ya |
Ninu oro
Gomina egbe naa, Musiliu Dasofunjo topo mo si Jogunomi, oun naa ko fi idunnu e
pamo lojo naa, o ni loooto ANTP duro gege bi Baba to ti bi omo pupo, lara awon
omo naa ni Ambasedo, Imman, ati TAMPAN, o ni awon dupe pe gbogbo pe ki ANTP ati
TAMPAN maa foju ri ara won ti loo sokun igbagbe.
Dasofunjo ati Pastio Sunday Imisi nibi ayeye naa ni |
Lojo naa
ni won fun awon eeyan bii Oloye Lekan Alabi, Pasito Sunday Imisi, Baale Yemoja
atawon mi in lami eye. Lara awon to wa nibe lojo naa ni Oloye Jimoh Aliu, Oloye
Lere Paimo atawon agba osere mii in.
No comments:
Post a Comment