Onarebu Salvador lakooko to n gbowo naa fun ebi Baba Sala loruko Bola Tinubu |
Agba oselu nni to tun je asaaju
fegbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed ti sapejuwe gbajumo osere tiata, Alagba
Dokita Moses Olaiya Adejumo gege bi
akanda eeyan ti Olorun febun jinki ati pe ipa to ti ko nidii ise tiata ko nii
je kawon eeyan tete gbagbe.
Ninu ise ti okunrin naa ran nibi
ayeye asekagba oku alawada naa, eyi ti Onarebu Moshood Adegoke Salvador je
loruko e, to waye niluu Ilesa nipinle
Osun, lo ti so pe aderin pa osonu ni Baba Sala, opo awon ere to ti se nigba to
wa laye ni ko se fii se asadanu.
O wa ba ebi Oloogbe naa kedun pelu
adura pe ki Olorun forunke e. Bakan naa ni Bola Ahmed Tinubu tun gbe ebun owo
nla kale fun ebi naa eyi ti akobi Baba naa, Eni Owo Bamidele Adejumo gba loruko
ebi naa.
Nibi ayeye isinku naa lawon agba
osere bii Oloye
Jimoh Aliu, Oloye Lere Paimo (Eda Onileola) atawon osere
mi in ti pejupese.
No comments:
Post a Comment