Awon araalu ni ki Osinbajo fokanbale APC lo maa wole lodun 2019 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 9 December 2018

Awon araalu ni ki Osinbajo fokanbale APC lo maa wole lodun 2019
Ojogbon Yemi Osinbajo
Awon araalu nipinle Eko ti fokan igbakeji aare lorileede yii, Yemi Osinbajo bale pe didun ni osan yoo so fun egbe oselu APC ninu ibo aare to n bo lodun 2019.

Awon eeyan ohun soro iwuri lakooko ti Ojogbon Yemi Osinbajo bere ipolongo ile si ile ni agbegbe Ogba, niluu Eko, lojo Abameta, Satide nibe ni won ti so fun un pe awon setan lati fi ibo won fun Aare lati se eleekeji, ki o le baa gbe awon debi giga gege bi erongba e.

Arabinrin Modupeola Adedeji, to je okan lara awon olugbe ni Oluwole local Estate ni Ogba so pe Aare Mohammadu Buhari ati igbakeji e, Yemi Osinbajo sa ipa won latigba ti won ti de ijoba, bo tile je pe awon naa mo pe omi po ju oka lo, o ni ireti wa pe ti won sejoba eleekeji, irorun ni yoo mu ba araalu.
Osinbajo laarin awon araalu


Ogbeni Tiwalade toun sise aranso iyen telo so pe inu awon dun si bi Osinbajo se n se ipolongo ile si ile, o ni iyen tumo si pe won ka awon araalu si, o ni teletele bi won se maa n se ipologo lona kan ki i je kawon araalu le foju rinju pelu won, lati bawon so nnkan tawon n fee.

Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo ti wa muu dawon araalu loju pe gbogbo ileri won lawon yoo muse fawon eeyan, ati pe awon yoo mu won de ile ileri.

Ko to to akoko naa, ni Ojogbon Yemi Osinbajo ti bawon omo egbe naa soro ninu ogba telifisan LTV niluu Eko pe ki won ma se da awon ajegudu jera ti won fakoko sofo fodun merindinlogun pada sijoba, nitori won ni nnkan ti won n se faraalu ju pe won wa jawon lole lo.
Oun tun ree laarin awon araalu


O so pe iyato to wa laarin awon eeyan naa ati Buhari ni pe ko wa lati jale ko si gba kawon eeyan jale ninu ijoba e sugbon awon yen wa lati ja araalu lole, lai si won lowo duro.

Osinbajo so pe “A ko gbodo gba awon to wa ji owo wa lati pada wa se ijoba mo, won ji gbogbo owo wa, won tun wa fee pada wa lati tesiwaju lati maa ji, ko si nnkan to joo, o ti to ge. Laarin odun merin owo ti PDP ji ko fee to bilionu lona irinwo dola, won wa tun so pe awon fee pada wa, ko si nnkan to jo, e ma fun won laye.

Igbakeji Aare salaye siwaju pe isoro kan soso to n koju wa lorileede yii ni iwa ibaje ki i se igbekale. O ni nitori ti ko ba si owo ba si owo, ko si nnkan ti won fee sagbekale e lori, idi niyi to ni won ko gbodo gba oniwa ibaje naa laye lati sejoba mo.

Ninu oro Pasito Yomi Kasali, to ja alakoso agba to n satileyin fun Ojogbon Yemi Osinbajo iyen PYO, o so pe o ti fee to milionu kan awon eeyan tawon jere okan won fun ibo aare to n bo naa, ati pe awon si n tesiwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages