Awon araalu to n fehonu han |
Boya lawon
araalu Ajegunle Araromi to wa loju ona Eko si Ibadan ti won wa labe ijoba ibile
Sagamu West, Makun, nipinle Ogun le gbagbe ose to koja ninu aye won, ojo ti koo
se ranti ni rara. Epe si ni won si fi n ranse sijoba Amosun.
Awon kan ni
won sadeede yawo ilu naa losan gan an ojo Aje, Monde. ose to koja, ti won si
bere si nii wole ati soobu to wa niluu naa lai fun won laaye lati mu nnkankan
jade.
Ohun to je
ki oro naa buruju ni pe se ni won fi moto ko awon olopaa wa sibe pelu ibon ni
owo won, tawon yen si bere si nii yinbon soke lati fi le awon eeyan sa. Nnkan
ti won so pe awon eeyan naa so ni pe latodo ijoba ipinle Ogun lawon ti wa, ise ti won ran awon lawon
waa se.
Pelu gbogbo
bawon eeyan ilu naa se gbarayile ti won n sunkun ti won si n wo bawon dukia won
se n baje loju won, awon ti won n wo ile ati soobu naa ko ri ti won ro, ti won
fi se awon nnkan ti won se lojo naa.
A se kekere
ni tojo naa nitori pe nigba to di ojo keji bigba teeyan mura ogun wa ba awon
araalu naa ni, nitori won ni lati okan lawon olopaa ko besu begba naa ti n
yinbon bo, nibe lawon araalu naa tun ti n sa asala femi won.
Iwadii fi wa
pe awon meji otooto nibon ba lojo naa ti won si wa ni osibitu nibi ti won ti n
gba itoju, ti won si ni won ti yo ota ibon naa kuro nibi to ba lara won.
Awon naa ni
Tunde Idowu ati Sola Badejo nigba tawon mii- in si tun farapa yannayanna. Ninu
oro Arabinrin Seriifat Ayodele to je okan lara awon olugbe iluu to ba wa so
pelu omi loju, ni gbogbo nnkan agbekele oun ni Amosun ti baa je to si je
iyalenu foun.
Obinrin naa
so pe lati odun to koja nijoba Amosun ti doju le ilu naa, o ni isoda awon ni
won koko wo, ti oro naa si wa nileejo titi di akoko yii.
Iyafin Ayodele
naa tun so pe ohun to je ki oro naa dun awon naa ni won ko fawon ni akiyesi
tabi akoko lati ko eru won kuro ki won to wa gbe igbese naa. O ni ile ti won ti
wo ti le ni igba pelu soobu.
Okan lara
awon olugbe ilu naa to tun ba wa soro, Sola Amos ni tie salaye pe ninu awon
olopaa to tele awon ti woon wa yinbon fi le awoon niluu ni Basiru Iyanda ati
Akimuu Soba pelu okan lara moto hilux ti won gbe wa ti nomba e jee EA 2817
Lagos, lara awon olopaa naa lo jewo fawon pe ise ti won ran awon lawon wa je.
A tie tun
gbo pe bi ko ba se opelope Olorun, o ku die ki okan lara awon ti ota ibon ba a
dero orun. Nigba ti Baale ilu naa, Oloye Tajudeen Aina Obe soro, o ni awon ko
mo nnkan tawon see fun Amosun to fi dojule awon lati odun to koja. Bee lo ni
lakooko tibo waye lodun 2015, se lo wonu ilu naa wa pe kawon dibo foun laimo pe
iya lo maa fi je awon gbeyin.
Okunrin naa
so pe opo ise tawon ti se lati bi aadorin odun ju bee lo seyin ni won ti ba je
yii. Bee lo ni ilu Ajegunle Araromi ti wa tipe, ko to di pe won te awon bii
Mowe, Ibafo do, babanla awon lo nile ibe, sugbon se lo ni won sadeede wolu pelu
katapila atawon olopaa ti kogberegbe ti won si da nnkan ru mo awon loju.
Olori ilu
naa wa ke si gbogbo awon omo Naijiria pe ki won gba awon lodo Amosun o, nitori
ijoba odun meje to ti lo inira lo fi ko bawon niluu naa, o ni oro naa si wa
nileejo tawon jo n faa kaakiri.
Nigba ti
oniroyin wa pe akowe iroyin nileese to n ri si oro ile, o so pe oga oun to je
komisanna ko mo nnkankan nipa e ati pe ka ni awon ba fee gbe iru igbese bee,
awon yoo ti so fawon tonile lati pale eru won mo.
Sugbon titi
di akoko ti a n ko iroyin yii jo, epe lawon araalu naa fi ranse se Gomina
Amosun, ti won si n so pe awon ko mo ibi tawon yoo tun ti bere.
No comments:
Post a Comment