Buruji Kashamu |
Buruji soro yii lakooko to n ka oro apileko e leyin ti won fa
owo e soke gege bi oludije gomina labe egbe oselu naa, eyi to waye ni Omo-Ilu
niluu Ijebu Igbo lojo Aje, Monde ose yii.
Gege bi okunrin naa se
wi, o ni oselu dabi ere idaraya kan to je pe to ba loo soke yoo tun wa sile, o
ni nnkan to n sele lagbo oselu lowo niyen, awon lawon ko nii gba ki idiwo ti ko
nii je kawon koju si nnkan tawon n se waye.
Bee lo tun so ninu apileko e pe nnkan to je awon logub tawon n se ni lati gbe ipinle Ogun soke ju bo se wa
loo. O ni oloselu to ni ipinle oun latile, ti inu oun si dun pe omo Ijebu,to si
tun je ojulowo omo ipinle Ogun tawon eeyan e si feran.
Oludije gomina naa wa so pe pelu iriri toun ti ni nidi ise oselu ati lati bi
odun meloo seyin toun si ti ran opo awon eeyan gbogbo eleyii ni yoo tun je ki
oun le dari ipinle Ogun bi won ba le dibo yan oun lodun 2019. O so pe gbogbo
ileri oun loun muse fawpn eeyan oun lati agbegbe ilu ijebu gege bi asoju won
nile igbimo asofin lati odun 2015.
Ise akanse to so pe oun ti se ti le ni aadorin bee loun tun mu
igbe aye rorun fun won pelu, eyi to je pe ko ti si eni to ni akosile bee ninu
awon ti won ti n soju ekun Ijebu nile igbimo asofin.
O wa seleri pe oun setan lati tesiwaju iru awon idagbasoke bee,
ati lati tesiwaju nibi ti Amosun baa ba awon ise akanse ipinle naa de.
Ninu oro alaga egbe oselu naa nipinle Ogun, Bayo Dayo so pe ojo
manigbagbe lojo naa je ninu itan awon eeyan Ijebu Igbo, bee lo je ojo tinu oun
dun ju lati nnkan bii ogoji odun toun ti wonu oselu.
Bakan naa ni Remi Bakare to je alakoso agba ipolongo ibo fun
Kashamu ati Abati igbakeji e se ikilo fawon eeyan e pe ki won ma se bawon eeyan
ja o, o ni ki i se nitori ti ojo tabi aileja sugbon ki won ma so pe awon lawon
koko bere ija.
Lojo naa ni won safihan awon oludije won lati ori Seneto, dori
asoju-sofin nile igbimo asofin, atawon omo ile igbimo asofin nipinle Ogun.
|
No comments:
Post a Comment