Sina Fagbenro lakooko to n bawon oniroyin soro |
Egbe oselu ti KOWA ti so di mimo pe awon ti gbaradi fun gbogbo ibo to n bo lodun 2019, ati pe gbogbo awon oludije won ni yoo jawe olubori nibi ibo naa.
Dokita Sina Fagbenro Byron, to je oludije fun ipo aare labe
egbe naa lo soro yii nibi ipade oniroyin ti won se lojo Furaide ose to koja. O
so gbogbo awon oludije won lo kun oju osuwon lati dipo ti won fee dije naa fun un.
Nibi ipade oniroyin ohun ni oludije aare naa tun ti so pe
igbe aye omo eda je oun logun ati pe awon to ti je alase lorileede yii ti kuna
nitori won ko mu ileri won se faraalu.
O ni gege bi egbe won to wa fun igbalode, gbogbo ona lawon
yoo maa sa lati rii pe awon tele ilana lati mu idagbasoke bawon araalu, ati pe
gbogbo awon nnkan ipenija tawon ba koju lawon yoo saseyori e.
Lori bi won se ni egbe apapo kan CUPP ti fowo si yiyan Alaaji
Abubakar Atiku gege aare fun ibo 2019, okunrin naa loun ko fee soro nipa e,
nitori ki I se ilana ati ofin ti won fi sagbekale egbe naa ni won tele.
O so pe bi won yoo tile daruko Atiku o lawon igbese ti gbogbo
apapo egbe lapapo ni lati fowo si to wa ninu ofin won sugbon ti won ko se, o ni
egbe awon yoo so bo ba se n loo, ati nnkan tawon yoo se lori oro naa.
Bakan naa lo tun so lojo naa pe eto atunto orileede ti gbogbo
awon eeyan n so je eyi to je oun logun ju boun ba le wole sipo aare, nitori yoo
je ki onikaluku yoo mo ibi to wa lorileede yii.
Sina tun so edun okan e lori bi aare Buhari se ko lati fowosi
iwe abadofin to nii se pelu ibo to n bo lona, o ni eyi tumo si pe won ni nnkan
labele nipa ibo to n bo naa.
Ninu oro Dokita Bimbo Oyedokun to je alaga egbe naa nipnle
Eko lo ti so pe ko nii saye fun eeru lojo ibo, idi niyii lawon fi n gbaradi
sile ati pe awon oludije e ni yoo jawe
olubori labe egbe oselu KOWA.
Awon oludije egbe naa to tun wa nibi ipade oniroyin naa ni
Abang Emenyi, Akan Imoh, ati Tokunbo Akinbiyi.
No comments:
Post a Comment