Babatunde Olalere Gbadamosi |
Laipe yii ni Okunrin naa gba wa
lalejo, nibi to ti ba wa so nipa erogba e lati dije atawon nnkan to nii lokan
fawon araalu ati ona ti idagbasoke se le tubo ba ipinle naa,to ba fi le wole
lodun 2019. Awon oro to ba wa so niyii.
Mo ti n gbaradi fun ibo to n bo
Mo ti n se akitiyan lati gbaradi fun eto idibo to n bo lona
lodun 2019. Lara awon nnkan taa n se ni pe, a n bawon araalu soro jakejado
ipinle Eko, lati ori awon lobaloba titi dori gbogbo awon mekunnu patapata lati
le je ki won mo gbogbo eto ti a ni sile fun won lori bi a se maa so ipinle Eko
di otun.
Lara awon eto taa si
ni sile nii se pelu ina monamona, opopona to ja geere, omi mimu, eto imototo,
eto ileewe awon omo wa, eto ile olowo pooku, ilera ofe, eto ogbin ati ounje,
eto irin ajo afe, eto ileese aladaani ati eto amuludun to maa kari gbogbo
ipinle yi patapata.
Gbogbo awon nnkan ti mo menuba yii la fee gbe awon eto oro aje ipinle Eko lee lori, nitori
pe lowolowo bayii, ipinle Eko ko ni eto oro aje kankan to gun rege, bi ko se kijoba kan maa fun awon
araalu bi aso, ki awon maa fon owo jade lara won bi omi, omi si ti n tan lara
bayii, ko si owo mo lowo awon araalu, a ko si seto mii in fun won lati maa se oro aje.
Oludije gomina labe egbe oselu ADP naa ni |
Isejoba AD si APC lati odun
mokandinlogun seyin
Nigba ti won koko bere, se laa lero pe gbogbo eto isejoba ti
baba wa, Oloogbe Obafemi Awolowo gbe kale ni won maa tesiwaju e lati sejoba ti
won, sugbon bi ojo se n gun ori ojo la n ri pe gbogbo oro Awolowo ti won n so
ni ko si otito kankan ninu e, iro lasan ni.
Gbogbo awon nnkan ti won n se patapatapa lo lodi si agbekale
Awolowo. Oloogbe Obafemi Awolowo seto oro ileeko ofe fawon omo wa, sugbon nigba
tawon wonyii wole, se ni owo ileeko n ga soke sii. Awon naa pe nile eko ofe loooto,
sugbon sibe awon obi atawon alagbato si n san awon owo kookan gege bi owo ile
eko. Eko ti won n fawon omo yi nikan ni won ko san owo e. gbogbo eyi toku
patapata ni won n san owo e, atawon eyi ti a ko lero la tun n san owo e. iyen
gan an ko si so pe ki eko ti won n fawon omo wonyi tun dara ju ti tele lo, se
lo tun n baje sii, ileele lori yepe lawon omo n jokoo si, gbogbo paanu ileewe
lo ti ja tan. Awon oluko gan an ko lo si idanilekoo nitori tijoba ko seto e fun
won.
Iru eko tawon omo wa n gba nileewe ijoba wonyii ni ko si
nilana eko igbalode bayii. Idi ni yii to fi je pe ko sawon omo to se e fi
yangan lawon ileewe ijoba wa mo, a si gbodo pada lati wa se atunse, a si ni
lati gba awon oluko to po ju iye ta a ni lasiko yi sise. A tun ni lati ko
ileewe to po ju iye ta a ni bayii lo, nitori pe awon omo wa lasiko yi ma n wo
moto bii meta ki won too de ileewe won, yato si pe won femi awon omo wa wewu,
yoo ti re omo mi ko too de ileewe, oorun lo si maa lo maa sun to ba de ileewe.
Awon nnkan yi ko gbodo maa tesiwaju. Iru ise ti Alaaji
Jakande se nigba ti won koko de ijoba lodun 1979 la gbodo se bayii nipa pe ka
ko ileewe sii, iyen sawon agbegbe tawon eeyan ba n gbe nitori kawon omo ma baa
le maa rin irin to poju ki won to de ileewe.
Egbe oselu APC ko le sejoba titi lai
Loooto lemi naa gbo pe won so bee sugbon egbe kan ti so iru
e ri pe awon lawon yoo sejoba fun ogota odun, iyen egbe tawon eleyii gba ijoba
lowo won, sugbon nigba ti Olorun maa gbe ogo e yo, won ko lo ju odun kan leyin
ti won soro yi lo.
Eyi tawon APC naa n
so yii, ase ni won n pa fun Olorun, Olorun a si fagbara e han won.
Idi ti mo fi jade dupo gomina
nipinle Eko
Erongba mi da lori kawon araalu ri ba tise, ki won ri ona
gbe gba, kawon onisowo maa ri ere oja, kawon onise-owo maa ri owo gidi pa,
atipe kawon araalu tun le maa ni ilosiwaju, ki won si maa saseyori.
Se e mo pe emi gan-an
funra mi, onileese aladaani ni mo je, ise ta a si n se naa fawon itesiwaju ta a
n ri nibe. E je ki oro mi ye e yin, itesiwaju ta a n ri ki i se tori awon nnkan
tijoba se o, rara, paapaa julo, laarin gbogbo nnkan tijoba fi n foju wa ri naa
la si n ri ba tise, ta n ri ona gbe gba.
Sugbon sibe, ki i se gbogbo wa ni Olorun fun loore ofe yi,
awon ti won ko ti i ri iru oore ofe bayii la a fee sise fun lati ri i pe awon
naa n ri ounje je daadaa, won si tun n je ajeseku.
Fun eni to ba mo ipinle Eko latile, won a mo pe ilu oro aje
ni, karakata lawon nnkan ta a n se l’Eko, ko si nnkan mii in ta a tun n se ju
iyen lo.
Lati bii ogorun-un odun le seyin, la ti ri ka ninu awon iwe
tawon Oyinbo n ko jade, pe ilu karakata niluu Eko. Kaakiri lawon eeyan ti n wa
ra oja, tawon mii-in si n wa taja. Nigba tawon Oyinbo de, awon naa tun n ba wa
dowopo. Nigba ti won ri adun nibe, ti won n ri awon ere repete je won pinu lati
maa sakoso e.
Awon ti won lawon n sejoba lati
bii odun mokandinlogun seyin ni won ba eto oro aje ipinle Eko je, nitori pe ko ye won, ati pe won ki
i se omo aje, won ko sowo ri.
Nigba ti mo wa ni kekere, mo kiri oja laarin Eko yii, mo ti
kiri isana ri, mo kiri abela (candle), Bisco, Suga, Miliki laarin Eko ati niluu
Ikorodu. Bee ni mo tun ta aso ni Kota-Ariyo, mo ta ike ati oja pepeepe, tawon
obi mi fi n ko mi bi mo se le maa sowo lati jere.
Nigba tawon wonyii de, to di pe gbogbo awon to n se oro aje
ni won n ba ja, ti won so pe ole leni to ba n taja legbe titi, paapaa awon to n
kiri oja. Awon nnkan wonyii ni ko ye mi bi won se n pe gbogbo eeyan ni ole.
O si je ko ye pe awon
ara a bi yi ko mo nnkan ti Eko n je. Eko ko si le ye won tori pe ati eyi to
dagba ju ninu won paapaa, won ti dagba tan ki won to o wo Eko wa, won ki i se
omo Eko. Eni to ba si je omo Eko ko nii ki awon to n taja mole ko maa le won
danu, ki won maa ti won mole lori pe won n sowo. Nnkan ti mo fee se ni pe mo fee
je ki ilu Eko pada sipo gege bi oluuya eto oro aje (Economy capital) nile
Adulawo.
A ni lati se awon
nnnkan ta a ko se ri, nitori naa, ka tete gba a mu. Eto oro aje gbodo rorun
latari ina monamona. A ni imo ta a le fi se ina monamona ti ko nii seju. Pelu
pe inu omi l’Eko wa, a ko tun ri omi mu.
Gbogbo ijoba ibile kookan la maa se omi si. Bakan naa, eto
igbokegbodo laarin ipinle Eko ti wa soro fun gbogbo eeyan bayii, laarin
sunkere-fakere la maa n wa lojoojumo, a le lo wakati meta si merin lojukan
soso, paapaa julo awon to n gbe lona Badagiri (Badagry).
Se lo dabi pe won
ti yo won soto kuro ninu ijoba ibile Eko ni, nigba tijoba ko se ona fun won. A
fi ki eni to ba fee lo si Badagiri bayii ti da wakati mefa soto to maa lo oju
ona, ko too debe lati Eko, gbogbo nnkan wonyii la maa se.
Eto oko oju omi to maa le ko awon ero to po la maa ko wole,
ti gbogbo e ma maa sise pada. A tun maa ko Feri to ma maa gbe awon eeyan
kaakiri. A tun maa se reluwe lati Badagiri de Epe atawon agbegbe mii-in, ki eto
igbokegbodo le rorun fawon araalu.
A maa tun lawon
ileese kan to je pe koto oju titi ni won ma maa wa kaakiri lojoojumo, ki won le
maa tun un se lesekese. Gbogbo awon nnkan to je tijoba ibile patapata la maa da
pada fun won. Awon nnkan bii oja, ibudoko, odo-eran, oro eto ilegbe (tenement
rate), atawon nnkan ti ofin so pe ojuse ijoba ibile ni la maa da pada fun won,
konikaluku si di omu iya e mu.
Owo to n wole sapo ijoba iyen IGR ti won n so pe
ojoojumo lo n po sii, idi to fi n po si ko ju pe gbogbo nnkan to je tijoba
ibile nijoba ipinle ti gbese le. Nigba ti won ba gba a lowo won, o di dandan ki
owo won po si, ki tawon ijoba ibile si dinku. Latari idi eyi, gbogbo eto won la
maa da pada fun won.
Idi ti egbe ADP se fojoojumo tawon
yo ninu ipolongo ibo
Ko si asiri kankan bi ko se pe egbe APC ati PDP, egbe kan
soso ni won. Eka egbe oselu APC ni PDP je, iyen nipinle Eko, mi o le so ipinle
mii-in, gbogbo e si lawon araalu mo, nitori pe won ti ri bi nnkan se n lo, bo
si se wa naa niyen kaakiri.
Ko siyato ninu awon mejeeji, awon araalu si ti pinu pe awon
ko le ba egbe oselu mejeeji se mo, idi ni yii tegbe oselu ti wa, iyen Action
Democratic Party, ADP fi n ta yo. Bo se wu awon omo egbe won ni won se n
soda, ti won ba se PDP lonii- in, won a tun se APC lola, o ti fi han pe ko
siyato laarin awon mejeeji.
Ti e ba si awon ti
won jade lati dije lawon egbe oselu mejeeji yii, gbogbo won jo n rin ni, tori
pe ore kori-kosun ni won. Awa ko ba enikeni se ota, sugbon a ko le ledi apo po
pelu awon to n fi iya je awon araalu.
Idi niyii ta a fi n so pe ADP ni ona kan soso to tun se e
fowo soya le lori, iyen ti oloyinbo n pe ni Credible Alternative.
Ko si ajosepo kankan laarin emi ati
PDP
Mi o ni ajosepo kankan pelu egbe oselu PDP. Awon PDP ni
oludije ti won, awa naa ni oludije ti wa, ko si nnkan to fee pa wa po. Loooto,
egbe oselu PDP ni mo wa tele, loooto, mo si lawon eeyan nibe ti mo si n ba sere
gege bi ore, sugbon sa, ko si nnkan ti a jo n ba ara wa se.
Isoro loro baba so pe mu ba eto
oselu
Oro ‘baba so pe’ je nnkan to n mu isoro to po bawon araalu
latari pe gbogbo owo to ye ki won fi se nnkan siluu, awon baba ti won n ‘so pe’
yen ni won n ko gbogbo owo fun. E gbo, nigba ti olori awon egbe oselu APC so pe
ki i se pe gomina ko sise, o n sise, sugbon ko toju awon omo egbe. Awon wo lomo
egbe? Egbe ti won n so yii, awon funra won naa ni, awa ko si ni baba kankan to
n ‘so pe’ fun wa, awon araalu lo n ‘so pe’ fun wa, awon omo Eko lo n ‘so pe’.
Tawon omo Eko ba si ti n ‘so pe’, a gbodo maa se ti won ni. Awa ko ni orisa
kankan ta a n bo ninu egbe ADP ni kooro tabi gbangba, bi ko se pe ka se nnkan
tawon araalu n fe.
Emi naa fowo si eto atunto lorileede
wa
Eto atunto ijoba orileede Naijiria ti wa a se koko, o si je
nnkan ti a gbodo ri i pe o di sise, tori pe teletele ri, nigba ti onikaluku di
omu iya e mu, iyen ijoba rijiona (Western Region) nigba yen ni won da telifisan
akoko alawo dudu sile, paapaa julo papa isere, awa la koko nii, iyen Liberty
niluu Ibadan. Igba tonikaluku wa laaye ara e ni won se awon nnkan wonyii,
sugbon nigba to di pe a bere ijoba apapo lo di pe a ko le da nnkan se mo.
Igba ijoba rejiona la da Fasiti tiluu Ife sile, igba yen naa
ni won si Ibudoko ori omi ti Apapa, leyin ogun odun ni ijoba apapo sese ri
Tincan se. a maa ri i pe ilosiwaju to po maa de ba wa, tonikaluku ba duro lori
owo e.
Nipa ajo eleto idibo INEC
Ajo eleto idibo, iyen INEC bi won se wa lowolowo bayii, awon
ti won ko sibe ko le seto idibo to maa muna doko ti ko ni si madaru nibe. Nitori
pe olori INEC bayii, adugbon kan naa loun ati Aare Muhammadu Buhari ti jo wa.
Egbon Aare ilu nipa to n ko ninu ajo naa. Ti a ba ri madaru ti won se nipinle
Ekiti ati Ondo ninu eto idibo to koja yi, bawon oloselu se n ra ibo ni gbangba,
ti INEC naa si ri, tijoba ko si se nnkankan nipa e, o ti fi han pe won ni
erongba lati se eto idibo nirowo-irose lodun to n bo ni won n ba bo.
Idi ti Buhari fi ko lati fowo siwe
abadofin to nii se pelu ibo to n bo
Idi ti won ko se fee fowo si ti farahan, nitori pe a ti ri i
l’Ekiti, a si ti rii l’Osun. Awon ise ti won se moku-moku naa ni ko nii je ki
won fowo sii. Bi e ba si wo eto idibo to
gbe won wole, e maa ri i pe se ni awon okodoro oro kookan bere sii jade lenu
ojo meta yii, ida marundinlogorin (75%) awon to fibo gbe Aare Buhari wole ni
won ko niwe idibo nigba ti won dibo, awon ti won si dibo fun won, Oke-Oya lohun
ni won si poju sii. Aare ko si ni fe ki won lo ninu eto idibo to n bo lona yi
nitori pe o maa han gbangba sawon araalu.
Amoran mi fun araalu
E ma ta ibo yin o, eyi ti e ba ta ti fihan pe iya le fi je
awon omo yin. Bi e ba gba owo ki e too dibo, ko si nnkan teni to fun un yin
lowo tun fee se to ba de be. Won ti san owo ibo ti e di, ki le si tun n wa bi
won ba wole. Olorun ko ni je ka loo soko iparun.
|
No comments:
Post a Comment