Pasito Adeseye Senfuye |
Gege bi atejade ti Ogbeni Adeniyi
Adeloye to je oluranlowo pataki fun eto iroyin fun oludasile ijo naa, Pasito
Adeseye Senfuye fi sita, o salaye pe gbogbo awon eeyan to ba wa sibi ayeye naa
ni ireti wa fun un pe won yoo mu ebun lo sile.
Bee lo ni ko nii se pelu esin, ilu
tabi oselu, gbogbo awon eeyan ti Olorun ba fun nu oore ofe ni didun losan yo so
fun won lojo naa. O salaye pe awon ko sese bere eto naa, o ti le lodun meloo
kan seyin tawon maa n bo awon araalu, kawon naa le sodun pelu ayo ati idunnu.
O ni igbagbo oludasile ijo naa,
Pasito Senfuye to fi sagbekale eto olodoodun naa ni wa laaye kawon eeyan naa si
wa laaye pelu.O ni ohun ti akori todun yii dale lori ni Jesu bo awon eeyan. O
ni Jesu leni akoko to bo awo eeyan, ipase e lawon naa si n tele.
Adeloye ni lodun to koja awon eeyan
bii egberun merin lawon seto naa fun sugbon todun yii tun ti loo soke si
egberun marun un. O ni Diakoni
Kayode Ogunjimi to je alaga igbimo
eto naa ti mura sile pelu awon eeyan e.
No comments:
Post a Comment