Dapo Abiodun |
Bi iroyin to n loo nigboro yii ba le je ooto o se e se ki oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APC nipinle Ogun, Dapo Abiodun padanu anfaani ti won fun un lati dije ninu ibo gomina lodun 2019.
Gege bi iroyin to te wa lowo,won
fesun kan okunrin naa pe ko fiwe eri pe o loo se agunbaniro iyen NYSC sile eyi
ti won lo tumo si pe ko sin orileede baba e, leyin to jade ni yunifasiti niwongba
to je pe ojo ori e nigba naa si le lo.
Bee ni won lo paro ninu iwe to fi
gba foomu pe oun ko niwe eri yunifasiti kankan, eyi ti won lo fi tan egbe oselu
to ti jade ati ajo eleto idibo INEC
Iwe iroyin oloyinbo kan ti won pe ni
PREMIUM TIMES lo tu asiri oro naa sita, latigba naa lo si ti n je kayefi fawon
omo egbe oselu APC nipinle Ogun.
A o ranti pe ninu ibo abele iyen
pamari tegbe oselu APC se ni won ti daruko Dapo Abiodun gege bi oludije won,
eyi to da wahala sile laarin Gomina Ibikunle Amosun ati Adams Oshiomole to je
alaga egbe naa lapapo.
Idi ni pe Amosun yari pe Abiodun ko
lawon mu sugbon Adams Oshiomole so pe oun ni awon to seto naa mu pe o wole,
latigba naa ni ede aiyede ti bere, ti Gomina seleri pe oun ko ni sise fun Dapo
ninu ipolongo to n lo lowo yii.
Nnkan to sele yii lo mu kawon omo
eyin Amosun kan binu fegbe APC sile loo darapo mo APM, nibi topo won ti loo
dije fun ibo to n bo lona yii.
Pelu bi nnkan se n loo yii, afaimo
ki oro naa ma dele ejo, nitori bi won se ni awon oloselu atako kan atawon ti
won jo wa ninu egbe naa, tinu won ko dun si maa gbe loo sile ejo.
Opo awon to gbo nipa isele naa ni
won so pe eedi Amosun lati ma se je ko dije fun ipo gomina lo n di Dapo
Abiodun.
Latigba taa ti gboro naa, lati gbe
igbese lati gbo tenu Dapo Abiodun sugbon okan lara awon amugbalegbe e fun
iroyin, SF Emmanuel Ojo so pe awon yoo gbe atejade kan sita lori oro naa laipe yii.
No comments:
Post a Comment