Jimi Agbaje |
Oludije fun ipo gomina labe egbe oselu PDP nipinle Eko, Ogbeni Jimi Agbaje ti
fesun kan ijoba ipinle Eko ati ileese to n ri si patako ipolowo iyen Advertisement
Agency (LASSAA) lori bi won se dide ogun soun, nipa bi won se n wo awon patako
ipolongo oun kaakiri ipinle naa.
O soro yii lakooko towo te marun un
ninu awon osise naa lojo Aiku Sannde ti won si fawon le awon olopaa to wa
lagbegbe Pedro, Somolu, nipinle Eko.
Oruko awon osise towo te naa ni Julius
Opebenyo, Tunde Akanbi, George Benson, Yinka Adejuwon ati Saba Edgal. Won ni
owo te won nigba tawon eeyan ri won ti won ko awon patako naa sinu moto nla kan
lagbegbe Third Mainland Bridge.
Bo tile je pe moto nla ti won fi ko
patako ku die ko sa mo awon eeyan lowo, sugbon ti ori tako won, bee la tun gbo
pe awon osise LASSAA towo te naa wo aso
ise pelu kaadi idanimo ileese won lowo.
Nigba to n soro nipa isele
naa,Oludije labe egbe oselu PDP nipinle Eko naa so pe o ti le ni ogorun un patako ipolongo won lo
ti dawati sowo awon osise LASSAA naa.
O ni ijoba tiwa-n-tiwa ko faye gba
iru nnkan bee. O ni loooto ni won polongo ijoba demokiresi sugbon won ko fi
huwa rara bigba ti won fi n ba nnkan je ni.
O salaye pe gbogbo awon ohun elo
ipolongo oun lawon osise LASSAA yii baje ti won ko si fowokan ti Babajide
Sanwoolu, tawon jo je oludje gmiina.
Ninu atejade kan ti Ogbeni Felix Oboagawina to je alakoso feto iroyin fun Jimii Agbaje gbe jade lo tun ti sapejuwe iwa tawon LASSAA naa hu gege bi eyi tii ko bojumu. O ni iwa odaju ni won hu, o si ye ki won fofin gbe won.
O wa ro awon olopaa lati sise lori awon
towo te naa, ki won si fi won jofin.Bakan naa la gbo pe Jimi Agbaje ti so pe
kawon osise LASSAA naa da awon patako ipolongo naa pada sibi ti won ti ko won.
No comments:
Post a Comment