Alakoso gbo-gbo-gboo fun ipolongo fegbe oselu ADC nipinle Ogun, Oloye Anthony Ojesina ti so pelu idaniloju pe oludije fun ipo gomina labe egbe oselu naa, Gboyega Nasir Isiaka topo mo si GNI, ko nii bawon dasa ko fowo ra ibo lowo awon araalu fun ibo to n bo lodun 2019, o ni kaka bee awon araalu lo maa dibo won fun un.
Okunrin naa
soro yii lakooko to foro jomitoro oro pelu oniroyin wa, o so pe gbogbo eni to
ba ti n ra ibo, to n gbowo lowo oloselu ko to dibo fun un ta ojo iwaju e ni,
nitori ko si nnkan ti oloselu naa fee se to ba wole ju pe ko wona lati gba owo
to na wole pada, to si le fiya je araalu.
O ni gbogbo
enu loun fi so pe oludije toun sise fun un,GNI ko ni bawon fun araalu lowo
nitori ki won le dibo fun un ati pe kojo ibo de lawon araalu n duro de ki won
le le ijoba to wa lode yii lo.
Ojesina
salaye siwaju pe gbogbo awon araalu lo mo pe igbaketa ti okunrin naa yoo jade
dupo niyii, o ni igba akoko to jadem ipo keta lo se iyen lodun 2011, nigba to
tun jade lodun 2015, ipo keji lo so pe o se sugbon idaniloju wa pe lodun 2019
oun ni yoo jawe olubori gege bii gomina.
O tun so pe
bi Amosun se fi dandan fa Akinlade sile
ninu egbe APM ko tun irun kankan lara won, iyen ko si so pe ki ibo Yewa Awori
pin si meji, nitori gbogbo awon oba alaye atawon baale ni won ti sadura ti won
ti fi atileyin won han si GNI gege bii ojulowo omo won ti won yoo gbarukutu tii
lati di gomina nipinle Ogun
Okunrin naa
tun so pe’ A o rii pe lati bi odun metalelogoji lawon Yewa Awori ti n wona lati
di gomina, Egba ti se, Ijebu ti se, akoko ti wa to fawon naa, idi niyii ti won
fi fimo sokan tawon oba alaye nile naa se da irukere won jo lati fi sadua fun
GNI, bee lawon ijoye naa se bee pelu.
Nigba to n
soro nipa erongba oludije e yii fun ipo gomina, Alakoso ipolongo naa so pe
Gboyega Isiaka je enikan to mo nnkan tawon araalu n fe, aarin won lo gbe dagba
ni Imeko oun naa si ti foju winna opo nnkan to mo pe o n je araalu niya, iru
won bayii lo ye fun ipo gomina, ti yoo tete wa ojutu sawon isoro to ba n koju
awon eeyan.
Bee lo tun
menuba lara awon eto ti GNI fawon eeyan ipinle Ogun, O ni akoko eto- eko je e
logun, nitori ipo to wa nipinle naa ko tee lorun, idi niyi to fi ni bi GNI ba a
se wole lodun 2019, eto apero nipa oro eko ni yoo koko gbe kale, nibi tawon
ojogbon, oluko atawon araalu yoo jo jiroro nipa bi ogo eto eko yoo se pada
sipinle Ogun. Bee ni won yoo tun sapero lori awon ileewe giga to wa nipinle
naa, iye to ye ki won maa san lowo ileeewe ti ko ni ju agbara awon obi lo.
Bakan naa lo
so pe ninu ijoba GNI atunto yoo de ba eto ilera lona igbalode, awon ohun elo to
ye nijoba yoo pese. Anthony Ojesina wa so pe iberubojo si wa fawon lori ipolongo tawon se yii, nitori
aimoye igba lawon kan ti wa kolu won nibi ti GNI ba ti polonbo, to je pe leyin
to ba kuro nibe lawon yen yoo da wahala sile, nipase bee, o ni won ti ran eeyan
kan lorun airotele, bee ni won tun si se awon eeyan kan nijanba sugbon awon ko
mo awon to n sise naa yala APC tabi PDP,
Okunrin naa wa
gba gbogbo awon eeyan ipinle Ogun nimoran lati ma se fibo won jona, bee ni ki
won sa fawon to ba fee ra ibo lowo won, nitori iparun ni won fee ran won lo, o
ni GNI lati egbe oselu ADC ni ki won dibo fun un.
No comments:
Post a Comment