Akinlade |
Lodun 2011, asa kan wa ti won maa n da ninu oselu, egbe oselu kan ni won fi dasa naa, iyen PPN, ti won ba fee tumo egbe naa nigba naa, won a ni pin pin lowo Nasir. Nnkan to si faa nigba naa ni wahala to sele ninu egbe oselu PDP laarin Gbenga Daniel ati Oloye Olusegun Obasanjo nitori awon oludije ti won fee fa kale.
Sugbon nigba
tawon omo eyin Daniel rii pe won ti sun awon kan ogiri, ko si fee si ona abayo
mo ni won se gba PPN iyen People Party of Nigeria loo, nibi ti Gboyega Naisir
isiaka ti jade gege bi oludije won.
Leyin ibo
naa, nnkan ko ri bi won se fee, bo tile je pe won rowo mu lawon agbegbe kan amo
ti gomina naa ko bo si,awon araalu kan pin owo GNI nigba naa laidibo fun un.
Irufe nnkan
bayii lo fee sele ninu ibo to n bo lodun 2019, nitori bawon omo eyin Ibikunle
Amosun to je gomina nipinle Ogun se yapa sinu egbe oselu mii in iyen APM nitori
owo won ko te ipo ti won n wa.
Ohun to si
faa, gege bi gbogbo wa se mo, ko se leyin bi awon igbimo to seto ibo abele labe
egbe oselu APC se so pe Dapo Abiodun lo wole fun oludije ipo gomina nipinle Ogun,
eyi to tako Onarebu Abdulkadir Akinlade ti gomina fee ko dije.
O tipe ti
won ti fa oro naa laarin ara won sugbon tawon oloye egbe niluu Abuja labe alaga
egbe egbe naa Adams Oshiomhole yari kanle pe Dapo Abiodun naa ni, ko seni to le
yii pada.
Aimoye igba
ni Amosun para Abuja to loo se ipade po pelu Aare orileede yii, Mohammadu
Buhari to je pe gbogbo e naa pabo lo ja si, idi niyi tawon omo eyin e tawon naa
sa fee fipa dipo oselu mu se loo sinu egbe APM nibi ti Akinlade ti jade gege bi
oludije won.
Iwadii tun
fi ye wa pe wahala kekere ko ni nnkan naa ti da sile laarin awon omo eyin
Amosun, nitori bawon kan se so pe lailai awon ko le fegbe APC sile loo si APM,
eyi ti won ko ti ri yanju di akoko yii.
Bee la gbo
pe awon Yewa Awori naa ti so pe awon ti gbon, nnkan to maa n daja sile lakooko
tibo ba fee waye ti ki i je kawon rowo mu, ko le sele lote yii, won Gboyega Nasir
Isiaka toun je omo won lawon yoo ti leyin, koda, a gbo pe won tun fi epe sile
feni to ba dale.
Won ni bigba
ti Akinlade kan fee wa fakooko e sofo ni, won ni ko pada loo to, ko tii kan,
boya o si le kan lojo iwaju.
Bakan naa
lawon omo egbe oselu APC naa so pe bawon araalu se pin owo Nasir lodun 2011, ni
won yoo pin ti Akinlade naa, nitori awon ti wa ni igbaradi fun ibo to n bo naa.
Idi niyii
tawon araalu to rawon omo eyin Amosun ti won domo egbe APM nibi ti won ti n jo,
ti won n yo pe won si ofiisi tuntun pe won kan fakooko won sofo ni, ko sibi ti
won n lo.
No comments:
Post a Comment