Oludije labe egbe oselu PDP nipinle Ogun, Seneto Buruji Kashamu ti so pe titi di akoko toun si n soro yii, oun si ni oludije kan soso tegbe naa ni fun ibo gomina to n bo lodun 2017.
Okunrin naa soro yii lakooko to n se ipade po pelu awon
oniroyin leyin idajo ileejo kotemilorun to waye niluu Ibadan. O ni idajo naa ko
so pe eni tawon jo n fa wahala ipo naa lo letoo bi ko se pe se lawon eeyan n so
isokuso leyin ti idajo ti waye.
Seneto naa so pe ileejo kotemilorun naa ninu idajo e so pe
ejo to wa niwaju oun ko so nipa eto idibo, nitori idi eyi oun ko le dajo lori
mimu oludije, o ni iyen ko ni nnkan tegbe PDP atawon eeyan gbe wa siwaju, oun
ko le gba ebe won wole nipa e.
O salaye pe awon alaimokan kan so pe nitori pe ajo eleto
idibo gba oruko awon oludije won wole fun ibo odun 2019 lori ase ileejo giga
apapo, eyi ti won ti gbe segbe kan bayii, idi niyii ti won fi gbese le yiyan
awon oludije won.
O ni oro naa ko ri bee rara nitori ileejo giga ti ekun Eko
ninu idajo won lojo kerinlelogun, osu kefa, odun 2016, eyi ti ko te igun keji
lorun.
O ni lojo kerin, osu karun un, 2017 nileejo da eja da
kotemilorun ti won pe ni, o ni bee naa ko tun te won lorun ti won si ro ileejo
lati tun sejo naa ni ojo kokanla, osu keje, odun 2018 ni ekun Eko bakan naa.
O ti wa so pe mimi kan ko le mi oun fun idije gomina toun ba
lo ati pe o da oun loju pe lodun 2019, oun lawon ni Amosun yoo gbejoba fun un.
No comments:
Post a Comment