Ki i se tuntun mo pe egbe oselu APM tawon omo eyin Gomina Ibikunle Amosun sa lo nitori won fee depo oselu pelu tipatipa ti se ifilole egbe naa bee ni won ti bere ipolongo won.
Sugbon
nnkankan wa to ye kawa omo Yoruba,taa mo nipa isedale wa mo nipa e daadaa, mo
si mo pe bee naa lori lawon eya kan naa.
Ko si nnkan
ti ote ko jo ninu aye yii, ituka lo maa n gbeyin e, bakan naa ko si nnkan
teeyan se laye yii to gbe,ile aye yii lonikaluku yoo ti gba ere ise owo e.
Bee nikan to
n sele si Amosun atawon eeyan e ninu egbe oselu, awon to tii leyin lodun 2015,
ti won fi gbe agbara lee lowo, awon naa ni won wa da eyin boo, ti won wa bere
si nii ge e je ni rikerike ara.
Bi ko ba ye
yin, awon to so fun un pe ko maa niso nile, to fi n foju Oloye Olusegun Osoba,
ti won so Baba naa di gba foga e, awon naa lo wa n fi yee pe aye pe meji ati pe
lopo igba ipo maa ju agbara ati owo lo.
Lojo Eti,
Furaide, ti won se ifilole ipolongo ibo fegbe oselu APM, tawon oloselu n daa
anko, tawon oba alaye kan to ye ka bawon nipo owo to je pe ete lawon eeyan
bawon lojo naa bere si nii n jo, ti won n yo pe egbe ti yoo gbajoba lowo Amosun
ti de.
Mo kan ranti
igba ti Gbenga Daniel naa se tie, tawon omo eyin e loo si PPN. Nnkan to
yamilenu ni pe pelu gbogbo ariwo APM, awon ero ojo naa ko tii po to tawon ti
Daniel, koda won ko to ilopo meji pelu bi won se nawo to, ofo nijo keji oja.
Ibeeere mi
ni pe sebi to ye kijoba maa na owo danu si niyen, nibi tiya ti n je mekunnu
tawon kan tori ipo, ti won tori pe won ki le mo pe won wa nibe nawo ni inakuna.
E gbo na, se
ti Abdulkabir Akinlade ko ba jade dupo gomina lodun to n bo, se o ro ara e pin
pe awon eeyan e ko ni faa kale lojo iwaju to fi wa di pe oro naa di tipatipa.
Pasan tawon
oloye egbe lapapo fi na Osoba ku lodun 2015, ni won wa mu jade lori aja ti won
fi pamo si ti won fi na Amosun bayi.
Ka ni Gomina
Amosun fee je ki won mo pe loooto ni nnkan ti won se ninu egbe oselu APC bi oun
ninu, o ye koun gan an binu kuro ninu egbe naa patapata, ko si fi ipo ti won fi
sile fun un fun won, nigba lawon eeyan yoo to mo pe
Okunrin naa binu tan,
sugbon bo se fese kan wa ninu APC, to fi eekeji wa ni APM, a je pe die ni
omokunrin e. idi niyii ti mo fi so pe gbogbo eyi ti won se yen Daniel se ju bee
lo, ofo si lo mu bo nibe.
No comments:
Post a Comment