Emi ko nii doju tawon eeyan mi bi mo ba wole- Owolabi Kola Balogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 23 December 2018

Emi ko nii doju tawon eeyan mi bi mo ba wole- Owolabi Kola Balogun
Owolabi Kola Balogun
Owolabi Kola Balogun,to je oludije fun ipo asoju-sofin ni ekun Abeokuta South labe egbe oselu PDP nipinle Ogun, ti seleri pe oun yoo rii pe oun mu iderun bawon eeyan oun, ti won ba fi le dibo yan oun wole lodun 2019,
O soro yii lakooko to n awon oniroyin soro niluu Abeokuta , O ni oun ti seto ti yoo igbe aye rorun fawon eeyan to wa labe e paapaa julo lawon igberiko, awon nnkan ti won yoo janfaani e, bi won ba le dibo yan oun.
O so pe ibi toun ti jade wa je agbegbe tawon ipile oloselu wa nitori idi eyi, oun ko le se nnkan ti ko ni bojumu fawon to wa nibe, gbogbo agbara lo ni oun yoo sa lati rii pe opo ipenija to koju awon to n soju, loun yoo wa ona abayori sii.

Gege  bo se wi, ijoba Muhammadu Buhari  ko se daadaa fawon eeyan  nipa eto oro aje  lorileede yii, O ni titi di akoko isakoso ijoba ko tii so nita gbangba lori bi adinku se n ba okoowo, to si n fa airise se fawon odo.

O tun salaye pe bi awon Boko Haram se n fojoojumo oawon eeyan, ti eto aabo n mehe je nnkan ta gbodo wa nnkan se si lorileede yii. O loun setan lati sise po pelu aare tawon eeyan ba dibo fun un. O lo si da oun loju pe Atiku Abubakar lawon eeyan yoo dibo fun gege bi aare.

Kola Owolabi wa pari oro e pe oun fee soju Abeokuta South ati ipinle Ogun nitori lati ja fun awon nnkan to ba je eto won. Oun si seleri pe oun ko nii doju tiwon toun ba de be.

No comments:

Post a Comment

Pages