Oludije sile igbimo asoju-sofin labe
egbe oselu PDP ni ekun Ado-Odo Ota, Onarebu Olusegun Monsuru Omosunmonu ti
seleri pe gbogbo ona loun yoo sa lati ri si eto ilera awon eeyan toun ba fi le
wole ninu ibo to n bo lodun 2019.
Okunrin naa soro yii lakooko to n ba
awon omoleyin e soro ni Iyana-Iyesi, Ota nipinle Ogun, nipa erogba e lati dije
fun ipo asoju-sofin labe egbe oselu PDP, O so pe o se pataki lati tete gbe
igbese pajawiri lori isoro to n koju awon eeyan agbegbe e nipa eto ilera.
O ni edun okan lo je pe ile iwosan kan soso to n sise yato si tawon
aladaani lagbegbe oun ni ti jenera to wa ni Ota. O ni gbogbo yooku loun le ka
si ile itoju nnkan pamo si, nitori yoo soro lati ri awon osise ijoba nibe.
Oludije naa tun so pe "
Mo fee ki e lo si Atan , Ado Odo , Iyana Iyesi , Ota atawon yooku nibiti won so pe awon ti n toju
awon alaisan, ki e wa beeere lowo won pe se won ni awon ohun elo ti won fi le
toju alaisan ni pajawiri. Boya won ni ohun elo fawon alaboyun, se moto pajawiri
ti won fi le sare gbe alaisan wa, eyin
eeyan mi, to ba je pe loooto ni, a ko le tesiwaju bayii, ti e ba dibo yan mi,
ti mo wole gbogbo awon nnkan wonyii ni mo maa se lati fi gba emi awon eeyan la.
"
Bakan naa lo tun menuba isoro airise
se to fojoojumo po si, o ni oun ma a le lagbara lati gba awon eeyan sise o,
sugbon oun yoo seto lati ro won lagbara eyi ti yoo le mu irorun ba aye won
paapaa julo awon obinrin atawon odo.
Ni ipari, o wa ro awon eeyan agbegbe
Ado- Odo Ota lati dide atileyin ki
erongba ala oun ko le di mimuse. O ni akoko niyi fun won lati dibo feni to ba
le se, ki won ba le tesiwaju.
No comments:
Post a Comment