Ibikunke Amosun |
Latigba ti oro oselu
ibo 2019 ti bere, lawon otokulu lawujo ti n foju inu wo nnkan to n sele, loooto,
o n sele kaakiri orileede yii, eyi to je emi logun ju nile Yoruba.
Bi a ba si ni ka woo,
ipinle Ogun lawon eeyan foju si ju lo, nitori wahala to n sele ninu egbe oselu
APC, bi won se yo owo Gomina Ibikunle Amosun lawo, ti won fi nnkan to n je egbe
han.
Loooto ero okan Amosun
ni lati je ki Yewa di gomina, gbogbo ibi to ba si n lo lo maa n fi Olorun bura
pe eyin won loun wa, awon lo gbodo je gomina nibi ibo to n bo naa.
A o ranti pe nitori e
lo se ni kawon agba Yewa-Awori sise lori eni ti won fee mu ko se gomina ninu
awon oludije won to n jade,kawon yooku si fowo sowopo pelu e.
Ise lokunrin naa se,
nitori lati duro lori oro e, sugbon awon asise to n se bayii ti fee kawon eeyan
maa beeere pe se loooto lo fee lati je ki Yewa di gomina.
Nigba ti egbe e ti so
pe erongba tie yato si tawon lori oludije gomina, ti won ti fa eni to wu won
kale, nnkan to ye ki okunrin naa se ni pe ko gba fun Olorun, niwongba igba to
je pe awon yen naa lo foun naa sipo lodun 2011.
Omo Yewa kan ti wa to
je pe odun 2011 lo ti n ba a bo lati di gomina sugbon tawon alagbara ko je ko
debe, to si wa je pe lara awon alagbara naa lo ni dandan ki okunrin naa jade
dije, kilode ti Amosun ko fowosowopo, to ba je pe o wuu bo se wi pe ki Yewa di
gomina, ipo ti won ti n ja fun un lati bi ogoji odun o le seyin.
Bi Amosun se yari
kanle to gbe oludije tie kale pe ko loo dije labe egbe oselu mi in, APM, se ko
mo pe ewu nla tun ni fun awon Yewa nitori ko si bi won se le fee see, won yoo
pin ibo won si meji ni bee naa iyapa yoo tun tibe waye. E si n so pe e fee ki
Yewa di gomina.
Bi a ko ba gbagbe, iru
nnkan bayii lo maa n sele ti ki i je ki erongba awon Yewa-Awori di mimuse lati
sakoso ipinle Ogun, ati pe mi o ro pe eni won ko gan an, atenuje ati nnkan ti
won yoo je lopo won wa, bi ki i ba se bee ni, won ko nii maa jin ara won lese.
APC ko lati fun Yewa
ni gomina, kaka ki won jo fenu ko o pe egbe to ba fa omo won jade ni won yoo dibo fun un, won ko see bee,egbe
mi in ti yoo mu ipinya bawon, ti ko ni je ki won de ibi ti won n fee ni won tun
tele.
To ba je pe loooto ni
Amosun fee ki Yewa di gomina lodun 2019, oselu tuntun yen ki i sara e, ona lati
ba nnkan je fun won patapata ni eleyii, oro sunnukun, oju sunnukun la a fi n
woo.
No comments:
Post a Comment