Wahala kekere ko lo n
sele ni Iraye, Ode- Remoo, nipinle Ogun, lori bi won se ni Oba Olatunji
Kalejaye to je oba iluu naa se fi aake kori leyin odun meta tile-ejo ti ni ko
fi ori oye naa sile.
Bo tile je pe nnkan ti
a n gbo ni pe won ni Oba naa ti gba ile-ejo ko-te-mi-lorun lo sugbon awon ebi
Sugbada ti won lawon loba ilu ohun kan so pe leyin tii idajo waye tipe lokunrin
naa sese loo sileeejo, nitori ko fee fipo naa sile.
Lojo Keedogun, osu
keje, odun 2015 ni adajo ileejo giga to wa niluu Sagamu, Adajo Ogunfowora gbe
idajo e kale pe ki Oba Kalejaye ma se pe ara e gege bii Nloku tiluu Iraye, Ode-
Remo mo ati pe aye oba naa ti sofo latigba naa loo.
Sugbon boya nitori ebi
Sugbada ti won pejo naa ko tete gbe igbese lati wa omo oye tuntun ni tabi won
ko tii setan ni lo mu ki Oba naa ko fi ja oro naa kunra, to si n se bii oba
alade lo laafin.
Iwadii tun fi ye wa pe
won ni o lawon kan ti won ti oba naa leyin lati ma se fipo naa sile, ti won si
so pe meji ti ku ninu awon eeyan naa bayii ati pe oun ti won so pe o fi oba naa
lokanbale bayii ni ejo ko-te-mi- lorun ti won so pe o pe si ibadan bayii.
Ninu oro Alaaji Tahiru
Oseni, eni odun mokandin laadorun, to je olori ebi Sugbada ti won so pe awon
loba naa to si, o je ka mo pe idile merin lo n je oba Inloku –Iraye, ni Ode-
Remo. Awon naa ni Somade, Sugbada, Sowomade ati Olubinjo.
Bakan naa lo so pe
latigba ti Oba Samuel Ademola Adesanya to wa lati idile Somade ti jade laye ni
aye oye naa ti sile ati pe ebi Sugbada loba kan, a fi bawon se gbo pe Olatunji
Kalejaye de lati iluu oyinbo ti ki i se ebi won joba lona aito.
Idi niyii to fi ni
awon gbe e lo sileejo giga kan to wa niluu Sagamu nibi tawon ti gba idalare pe
Kalejaye fipo naa sile ko to o si, o ni o fee maa fowo ola gba awon loju ni.
Ninu oro ti akowe ebi
naa, Awofeso Tope, o so pe latigba ti oro naa ti sele lawon ti bere si nii gbe
igbese, nitori awon ko fee ko da wahala sile lawon se towo ofin bo, lara ibi ti
won ti de ni ogba awon olopaa ni Eleweran niluu Abeokuta ti won ba won da si
oro naa, nibe lo ni awon ti gbo pe oba naa atawon eeyan e ti koko n gbe ayederu
leta kan kaakiri pe awon ti pejo ko-te-mi-lorun.
O ni nigba toro naa
feju daadaa ni won to gba kootu lo ati pe leta ti won n gbe kaakiri tele kii
sojulowo. Bee lo ni awon tun ko leta sileese to n ri oye jije ati ileese gomina
lori oro yii sugbon tawon ko gbo esi kan.
Ki oro naa ma baa di a
n gbo tenu enikan lo mu wa pe Oba Kalejaye lati gbo tenu e, oun ti oba naa ba
wa so lori foonu ni pe oun ko nii nnkankan ba wa so lori oro naa, o si pa foonu
e.
No comments:
Post a Comment