Egbe oselu Action Democratic Party
(ADP) ti eka ipinle Eko ti so pe ko si ooto ninu aheso tawon kan gbe jade pe
awon ti fowo si Alaaji Atiku Abubakar gege bii aare won fun ibo to n bo lodun
2019.
Ninu atejade ti alaga egbe naa,
Nasir Adewale Bolaji fi sita lojo Isegun
Tusidee lo ti so pe ko sigba kankan
tawon gba okunrin naa wole fun ipo aare ati pe Alaaji Yabagi Yusuf Sani si ni awon mo fun oludije aare won.
Okunrin naa so pe loooto lawon wa nibi
eto kan ti won se ni Muson, Onikan niluu
Eko lojo Aje, Monde nibi topo awon agbaagba Yoruba wa nibe, nibi ti won ti
jiroro lori ojo iwaju ile Yoruba.
Idi to ni awon fi wa nibi ipade naa
ni pe nigba ti ki i se nipa oselu ni won se pe e, won ni lati sagbega asa ati
ise ile Yoruba ni. Sugbon o ya awon leni nigba tawon iwe oloyinbo kan gbe e
jade pe awon fowo sii. O legbe awon ko gba Atiku wole o.
O tun salaye siwaju pe ipade naa tin
loo daadaa o, ko to di pe Dokita Remi Akitoye gbe oselu wo nigba to dabaa pe ki
awon to wa nibe lojo gba aba pe ki won gba Atiku wole gege bii oludije won nile
Yoruba.
O ni ki i se gbogbo awon to wa nibe
lo gba aba naa wole nigba ti ki i se egbe oselu
PDP nikan lo wa nibe lojo naa, aba naa lo ni awon eeyan ko gba wole. O ni boya ariwo tawon eeyan n pa a to dapo mo
tawon PDP ni won se roo pe won gba wole.
O ni bawo lawon eeyan se le so pe ADP
gba Atiku wole nibi tawon oludije gomina bii Babatunde Olalere Gbadamosi (ADP),
ati Mr Jimi Agbaje (PDP) atawon mii in wa, o ni iro nla ni jare.
Adewale so pe Omooba Uthman Shodipe to
dide to n ka nnkan ti won ti ko sile tele eyi tawon omo egbe oun ko mo nnkankan
nipa e lo so pe won yan Atiku.
|
No comments:
Post a Comment