Emi awon araalu lo je mi logun ninu ijoba mi- Sina Fagbenro Byron - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 5 December 2018

Emi awon araalu lo je mi logun ninu ijoba mi- Sina Fagbenro ByronOludije fun ipo aare ninu ibo to n bo labe egbe oselu KOWA, Dokita Sina ti so pe oun to se pataki julo ninu ijoba oun, bi won ba le dibo yan oun wole lodun 2019 ni emi awon eeyan, lati pese abo eyi ti yoo fi won lokanbale.

O soro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro nipa ipinnu gege bii aare orileede yii, O so pe ipo okan awon araalu ko bale rara nitori eto abo to mehe ninu ijoba taa n lo loo yii, opolopo si ni ko le foju e mejeeji sun mo.
O ni okan lara ise toun yoo koko se lati wa ona ti abo yoo se kaakiri orileede yii. 

Bakan naa lo so pe eto eko, ilera, ogbin atawon nnkan amayederun loun yoo rii pe oun fawon eeyan laifi ti eleyemeya se.

Nigba to n soro nipa nnkan ti egbe oselu KOWA naa duro fun un, Dokita Sina Fagbenro so pe oun tawon so ni pe ki ire ko wa, ki alaafia ko wa ati ire omo.

O ni nnkan meji lawon duro lee lori ninu egbe naa iyen akoko ni igbalode, gbogbo nnkan to ba ti ba igbalode mu lawon tele. Bee lo ni awon tun wa fun kawon maa ko ara won jo,awon ki i fara awon sile, idi niyii to fi ye ero ibanisoro lawon fi se isamisi egbe won.

O ni awon ti wa ni igbaradi fun ibo to n bo nitori awon araalu ti to awon egbe oselu meji kan wo ti won si rii pe ko si iyato kankan ninu won, won kan n ko idaamu ba araalu ni.

Okunrin ohun so pe iriri toun ni nidi oselu latigba toun ti wa ninu egbe PDP toun fi darapo sinu KOWA ti to foun lati se aare orileede yii, nitori oro ariwo ko ni bi ko se keeyan se nnkan ti yoo mu kidagbasoke bawon araalu, ki won si kuro loko inira ti won wa.

O tun salaye pe opolopo won lo ti wa ti won ti doju ti araalu ti won ko se nnkan to ye tawon eeyan si ti to won wo. O ni Buhari omo Fulani ni, Atiku omo Fulani loun naa sugbon oun omo Yoruba akoko ti to lati se nnkan Awolowo se, to fi mu idagbasoke ba araalu.

Bee lo so pe oun naa faramo atunto, iyen si wa lokan oun pe toun ba fi le wole bi atunto naa yoo se ya ni kiakia loun yoo ko se nitori o ye kawon eya kookan mo ojuse ara won.

Fagbenro waa lodi si asa bi won se fowo ra ibo lowo awon araalu, o ni ki i se nnkan to bojumu rara, bo tile je pe o ni ko dun mo awon to n gbowo fi dibo naa ninu sugbon ibi ti oselu ba awon eeyan de ni.

Lara ohun to so pe o wa lokan oun ni Idaboobo,Eto Eko, Ayika ti yoo fopin si isele awujo, ise igbalode to le pese owo ati oro Aje.

 O wa ro awon araalu lati dibo won fun egbe oselu KOWA  ninu ibo to n bo lodun 2019, ki gbogbo nnkan ti won n fee le te won lowo.
No comments:

Post a Comment

Pages