Mo setan lati soju awon eeyan mi nile igbimo asofin- Olumide Awolowo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 30 November 2018

Mo setan lati soju awon eeyan mi nile igbimo asofin- Olumide Awolowo




Okan lara awon gbajumo sorosoro ni Olumide Awolowo, eni to mo nipa tifun-tedo ise naa, idi niyii tawon ore e fi maa n pe ni Orobo Presenter. Sugbon laipe yii la gbo pe okunrin to tun maa n bawon kopa ninu fiimu Yoruba gbegba oselu, o si n dije fun asoju omo ile igbimo asofin ti ekun Abeokuta South labe egbe oselu AD ninu ibo to n bo lodun 2019.

Oniroyin wa ka okunrin to wa to di sorosoro oloselu naa mo koro, nibi to ti ba wa so erongba e lati dije fun ipo omo ile igbimo asofin nipinle Ogun. Ohun to ba wa so niyii.

Bawo ni Olumide Awolowo se di oloselu

Lakooko, oselu bere latinu Ile, de agbole titi de agbegbe de ipinle ati orile- ede. Bi a ba wa n soro oselu awarawa, inu eje lo wa, bee si ni a ko le koyan Oloogbe Jeremiah Obafemi Awolowo kere.

Sorosoro to danto  mi ni mi loooto, sugbon mo n se oselu pelu e lati bii ogun odun o le die seyin, oselu mi bere latigba ti mo ti wa  nileewe  Government Technical College,  Olobe, lati odun 1997.

Nitori pe mi o ki i fee kiya je eeyan lodo mi, mo tipase e di agbenuso fun awon akekoo nigba naa bi a se bere si wonu oselu niyen.

Awon ohun ti mo ni fawon eeyan mi

Mo fee fi eto ati ona iselu han awon eyan taarata laiyo awon akegbemi paapaa seyin. Awon eto ti mo ni dara gan an, o si to bii melo kan, awon abadofin kan wa ti a le se lati mu igbe aye iderun ba awon mekunnu.
Iro-ni-lagbara awon ojulowo odo, abadofin dida ileese sile loruko ijoba ipinle ti yoo mu irorun ba awon ara ilu. ilana igbalode la o fi see.
Awon abadofin lati gbogun ti iwa ibaje ati ijiya aito lawujo, ati beebee lo.

Idi ti mi o fi dije labe egbe oselu Olusegun Osoba

Baba mi ninu oselu ni Oloye Olusegun Osoba, sugbon bi mo se jiya to leyin won, ti mi o kuro lo segbe mii in yato si ibi ti won ba wa, ti pupo awon oloselu mo mi doju amin, se ni mo le so pe won ko pe mi si ipo tabi fun mi ni ipo kan ri, boya lati wa dupo tabi gba ipo.Mo wa pelu won titi di igba ti eni to ri iwulo mi ra foomu idije fun mi.

Ni afikun, inu egbe AD yi ni mo ti sise takuntakun ni odun 1998, nigba ti mo da egbe akekoo to n sise fun egbe AD sile ta a pe ni  STUDENTS ALLIANCE FOR DEMOCRACY (S.A.D) sile, boya lati ara iwa mi, ati jije olooto eniyan ni mo fi wa n jere re bayi leyin ogun odun.

Lakotan, nibi ti won dori oselu kodo sii loni in, ko le faye gba iru awa ti ko ni owo to maa fi ra ipo ninu oselu pelu gbogbo opolo ta a ni, nitori awon onisowo oselu lo po bayii ju awon to fee selu.

Egbe oselu AD lo maa wole gomina lodun 2019

Pelu gbogbo awon odo olopolo pipe ta a ko jo fun oselu takoko yii, ati pe oselu akoko yii ki i se egbe rara,eeyan la maa dibo fun, latari pe egbe ti feyin wa janle, mo mo daju pe egbe AD lo maa joko lori aga gomina nipinle Ogun ni 2019 lase Edumare nitori awon eto ati ilana egbe AD ko lafiiwe, eyin naa saa  ri ni eto isejoba Oloye Olusegun Osoba laarin 1999- 2003, ijoba wo lo tun dabi e lati igba naa.


 Awon to n fowo ra ibo

Hmmmm, awon ojelu to n pe ara won ni oselu ni won n se bee, nitori ti won ti kuna lati se ohun to to ati eyi to ye lakoko. Ni won fi n fi tipa-ti-kuu-ku du ipo oselu. Awon ni won mon on mo fi ebi pa araalu, won a tun da ounje die sita lasiko ibo, ki awon ara ilu tun le dibo fun won, Iwa to buruku jai ni.

Awada ko o, mo n dije fun ile igbimo asofin nipinle Ogun

Oro awada ko ni eleyii oo, mo n dije sile igbimo asofin tipinle Ogun lati soju Abeokuta South.

Egbe sorosoro fun mi ni atileyin

Mo dupe gidigidi lowo awon egbe pedepede nipinle Ogun ati ni Nigeria, nitori atileyin to gboopon ni won fun mi, Nitori pe won mo pe mi o ki i se aladanikanje atelero tara eni nikan.

Lati ori  alaga egbe wa, Olufemi Omilani Iyanda, dori omo egbe to kere ju, won mo pe ipo yi ki i se ti Olumide Awolowo, ipo egbe FIBAN ni.

Ki i se gbogbo nnkan lowo o

Beeni o, owo ni keke ihinrere, sugbon gbogbo e ko lowo. Mi o lowo sugbon mo ni eyin eyan rere lara, owo ti a gba laaye ninu eto ikopa lati yan eeyan sipo, lo je ka a ba ara wa nibi ta a wa yii. Ohun lo je ka maa sibodi, ohun lo faye gba awon ojelu ninu oselu ti won fi n ri eto iselu bii okoowo lati lowo.

Gege bi e ti mo pe entertainer ni mi, a o se eto si se awari awon ogoipinle Ogun latara ebun, ati ere idaraya fun awon tara won pe atawon akanda eyan.

O se e se fun wa lati gbajoba lowo Amosun
O se e se, nitori gbogbo araalu atawon oloselu ti mo pe egbe APC nipinle Ogun ko se daradara to, imo tara eni nikan ati adanikan je ni asole egbe won fi ba irinajo egbe naa je.

Mo nigbagbo ninu ajo INEC

Beeni mo nigbagbo ninu ajo INEC. Mo si mo pe won ko ni se ohun ti ko to, mo si tun gbadura pe Olorun yoo ran ajo naa lowo lati ko ogo eto idibo to n bo ni 2019 ja



No comments:

Post a Comment

Pages