Igbakeji
alaga fegbe oselu SDP nipinle Ogun, Ayo Jinadu ti so pe ko segbe oselu mii in
ti alafia ati isokan joba ninu e nipinle ju SDP lo, idi niyii tawon araalu fi
setan lati dibo gbe won wole lodun 2019
Okunrin naa
soro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro, o ni bi a ba ni ka soooto wahala
kekere ko lo wa ninu egbe oselu APC ati PDP, eyi to je ki ariwo won maa po
lojoojumo to si tumo pe won ko nii le rii yanju titi ti ibo yoo fi de,anfaani
nla lo si je fawon.
O salaye pe
egbe oselu SDP ti wa ni imurasile fun ibo to n bo naa pelu idaniloju pe oludije
won, Otunba Rotimi Paseda ni yoo jawe olubori nitori awon mo pe oun ni awon
araalu n fee lati gbajoba lowo Ibikunle Amosun.
O ni bawon
eeyan se gbarukutu ti MKO Abiola to fi jawe olubori labe egbe oselu naa lodun
1993 ni won yoo tun gbarukutu ti awon ninu ibo naa.
Nigba to n
menuba awon eto ti won fawon araalu, Otunba Ayo Jinadu ni,eto abo je awon
logunju ninu ijoba won nitori ti ifokanbale ba wa fun won, ti ko si wahala,
alafia gan an yoo de ba ijoba.
Bee lo ni
egbe awon ki i segbe ti yoo maa satileyin fawon toogi, gbogbo awon to ba ye ki
won wa lati maa pese aabo lawon yoo rii pe won sise won, bo ti to ati bo ti ye.
O tun so pe
egbe awon yoo tun seto eto eko ofe fawon omoleewe, eto ilera ofe naa yoo tun je
awon logun, ati gbogbo awon imayederun.
O wa ke si
awon araalu lati fadura ran won lowo, ki oludije won, Otunba Rotimi Paseda le
jawe olubori, nitori oun nikan lo le mu irorun ba ara ilu.
No comments:
Post a Comment