Alaga
fegbe oselu PDP nipinle Ogun, Bayo Dayo ti so pe awon gbo pe awon kan n pariwo enu pe awon ni oludije fun
ibo nipinle Ogun labe egbe oselu PDP, o ni kawon eeyan ma da won lohun nitori
won kan fakoko won sofo ni, nitori awon oruko ti ajo eleto idibo fowo si si wa
lowo awon ti won je ti Buruji Kashamu.
O soro yii lakooko to n sagbekale igbimo eleni
mejilelogoji to yoo sise lori ipolongo fun ti ibo oludije aare fegbe oselu naa,
Atiku Abubakar eyi ti yoo waye lodun 2019.
O
salaye pe awon ko nii ba enikeni ja nitori ebi kan lawon ninu egbe PDP, laipe
lawon yoo yanju gbogbo wahala to wa ninu won, tawon yoo si pada di okan..O
sapejuwe Atiku gege bi eni tawon eeyan n fee, oun nikan lo si le saaju awon
araalu lona to dara.
Nibi
ayeye naa to waye ni ofiisi egbe ohun lojoruu, Wesidee, ni won ti daruko Seneto
Buruji Kashamu gege bi alaga fawon igbimo naa, awon yooku ti won tun wa nibe ni
alaga
egbe naa funra e, igbakeji e ati Semiu Sodipo to je akowe won.
Awon
yooku tun ni Kunle Bolujoko ti yoo soju Ogun East, Kemi Ewedimu fun ti Ogun
Central ati Tajudeen Aina fun Ogun West, bee ni won tun lawon igbimo lawon
ijoba ibile Ogun to wa nipinle naa.
Ninu
oro Bayo Dayo lakooko to n sagbekale awon igbimo naa, o ro won lati jo sise
papo lati rii pe oludije aare fegbe oselu naa, Atiku Abubakar jawe olubori nibi
ibo to n bo lodun 2019.
O
so pe oun naa mo pe ko rorun lati gba agbara lowo awon to wa nijoba, sugbon
awon ni lati jo rin in papo ki won baa won araalu soro nipa ipinnu egbe oselu
naa ati idi ti Atiku fi gbodo wole gege bi aare nibi ibo ti yoo waye ohun.
No comments:
Post a Comment