Asiko yii ki
i se eyi to dara fun gbajumo onifuji nni, to tun ko Alaaji Sefiu Alao nise fuji
iyen Isiaka Akanji tawon oololufe e mo si Easy Kabaka tawon mii in tun pe ni Easy
Egba, nitori bi won se ni aisan ito suga ti won n pe ni diabetisi n yoo lenu,
ti won si ti feee ge ese e danu.
Titi di
akoko ti a n ko iroyin yii, osibitu FMC to wa ni Idi- Aba ni okunrin to ti fee
to aadorin odun wa bayi nibi to ti n gba itoju.
Gege bi a se
gbo, nnkan kekere ni okunrin naa koko pee ni bii osu mefa seyin ti aisan naa
bere, won lo fee lo gbe aga ko fi jokoo ninu ile e, lo fi ese sese,to si fi
oogun sii lati je ki oju ogbe naa kuro.
Ninu oro e,
nigba taa lo sabewo si ni osibitu to tii
n gba itoju, okunrin naa salaye
pe kayefi loro aisan naa je foun nitori oju bintin loun fi wo laimo pe yoo di
ohun nla bayiii.
Osiibitu
toun wa tele ni won ti ni ki won maa gbe oun bo wa si FMC nibe ni won ti je
koun mo pe aisan ito suga lo yo oun lenu ati pe ki i se pe o sese bere, eyi to
si je ki ese naa tii jera patapata.
Easy Kabaka
tun so pe nigba ti aisan naa le ju ti Sefiu Alao gbo, se lo dide iranlowo to ni
ki won gbe oun lo si osiibitu, to si tun sanwo ti won fi n toju oun.
O ni oun gba
ki won ge ese oun naa nitori inira toun je latigba to ti bere naa ti poju. O ni
gbogbo nnkan to de ba oun yii, oun ka si aisan irole aye, nitori ko sele ri bee
lo ni oun ko nigbagbo pe enikan lo se oun tabi oju aye ni.
Oga Sefiu
Alao onifuji naa wa bebe fun iranlowo awon omo Naijiriia rere lati saanu oun
nibi toun wa yii nitori owo nla lawon dokita n beere lowo fun gige ese naa.
Odu ni
Isiaka Akanni, Easy Kabaka lagbole fuji, agba oje lo tun je nidi e, oun atawon
bii Iyanda Sawaba, Waidi Akangbe ni won jo n mi igboro nigba ti okiki won si n
yo nidii ise naa.
Capt;
No comments:
Post a Comment