Bo tile je
pe oro naa ti pe ojo meta to sele sibe awon to wa nibi isele naa si n so pe
kayefi loro naa je nigba ti okan lara gbajumo maketa fiimu Yoruba kan ti a
foruko bo lasiri sadeede gbe majele je nitori ti iyawo e ko o sile.
Gege bi BO
SE RI se gbo, adugbo kan to ni oruko ni soobu e wa niluu Abeokuta, ore awon
osere onitiata ati olorin ni pelu, lopo igba lo si maa n gbe kaseeti orin awon
musulumi jade.
Okunrin ti a
n soro e yii kole si Obantoko bee won lo nise kan to n se tele ko to di pe oun
naa di maketa to n gbe fiimu atawon olorin jade, idi ise yii si ni Olorun ti
gbo adura e.
Iwadii fi ye
wa pe iyawo e ti won lo bi ibeji fun un lo ko o sile, tiyen si ko loo si ile to
ko pelu awon omo re. Eyi lo muu pinnu lati gba emi ara e.
Awon ti won
jo n gbe ladugbo ti won ba oniroyin wa soro so pe ki i se iyawo kan ni okunrin
naa fee, won ni iyawo akoko e ti koko kuro nile toun naa ko lo sile toun naa ko sugbon tiyen
ti pada bayii.
Lojo tisele
naa waye, won ni se lokunrin naa si gbogbo ilekun abajade sile, leyin naa lo
gbe majele ohun je, to si japoro latinu ile jade sita gbangba nibi tawon eeyan
ti tete ri i ti won si gbe loo si osibitu.
Yeye lawon
ore e to gbo nipa nnkan to se naa n fi se, won ni ko tii setan lati ku ni, ka
ni loooto lo fee gbemi ara e, ko ni loo silekun abajade tawon eeyan ti ri sile.Won
ni inu yara to wa lawon eeyan yoo ti roku e.
Bakan naa la
tun gbo pe se ni okunrin maketa yii tun loo ka iyawo e to fi sile mole tiyen n
gbe laarin aago mokanla ale, to si fee fi tipa wonu ile naa sugbon tiyen ko gba
fun un.
Eyi ni won
lo muu to fi fee fo ile obinrin lati le wole ni tipa, laaaro ojo keji lobinrin
naa lo folopaa mu maketa taa n soro e yii, bi ki i ba se awon to tete da si oro
naa ni atimole lokunrin naa ko ba wa.
No comments:
Post a Comment