Gege bi atejade eyi to te wa lowo ni igbakeji aare naa ti
salaye pe lopo igba oun ki i fesi lori nnkan ti won ba ko jade lori ero
ayelujara nitori awon mo pe iro atunda ni won maa n sagbekale e.
Sugbon idi toun fi fee fesi lori eyi ti won n gbe jade to
kun fun iro yii toun si ka awon to gbe e jade si gege bi oniyeye ati asiwere ti
ko fi awon idi oro e mule, to si ko awon nnkan ti ko mu opolo jade. O ni nitori o nii se pelu
oruko oun lo je koun tete fesi ranse.
O so ninu atejade naa pe onkowe naa ni ninu osu kin in ni
odun 2017 ti Aare Mohammadu Buhari loo si
orile ede United Kingdom nibi to ti lo gba itoju ati pe oun ni lati gba
ase gege bi ofin ati ilana sugbon toun ko see nitori esun bilionu marun un
naira owo ajo ijoba apapo to n ri si oro ayika iyen NEMA to ni o wa lorun e.
Osibajo so pe nipa esun owo NEMA ti onkowe naa fi kan
igbakeji aare pe o se kunakuna waye ninu osu kerin odun 2017 sugbon ti won
fesun kan an ninu osu kin in ni, won ni se o seese fun igbakeji aare lati loo
kowo bowe saaju akoko naa niluu oyinbo ti Aare ti n gba itoju. Eyi to tumo si
pe oro ti won gbe jade ki i se nnkan to ye ki eni to ni opolo maa gbe jade.
Lori oro ti won lo tun so pe Aare Buhari ti dagbere faye
niluu London ati pe enikan ti won n pe Jubril Al- Sudan to je elewon ni won fi
ropo, o ni won kuna pupo nidi e, nitori o ye ki opolo won so fun won pe
igbalode tawon oloyinbo pe ni Technology, bee ni won ko tun mo nipa ohun
akosile.
Igbakeji ni pelu eyi ti won so yii, o ti fihan pe alawada
kerikeri lawon eeyan naa, nibo ni won ti gbo ri pe won fi alaye ropo oku nibi
tojumo mo de yii. O ni to ba ri bee se won ko ti mo iyato nipase ohun ati
ihuwasi onitohun.
O wa so pe oro e ko le dun oun, nitori awon eeyan naa ti
jewo ara won pe nipa oro Nnamdi Kanu. O ni lawon eeyan naa so pe Aisat Buhari
to je iyawo aare ko le duro ti oko e mo nitori ayederu leni naa, esi to fi fun
won ni pe se won ti gbagbe pe losu kesan an taa lo tan yii ni toko tiyawo yii jo
wa po ni New York nibi ipade ketalelaadorin ajo United Nation.
Nigba to n soro lori esun owo NEMA ti won fi kan an, Osibajo
so pe oun fi gba ẹgbẹẹgbẹrun
awọn ọmọ Naijiria là nipa didoggbon gba bilionu marun un fun ipese ounje
pajawiri. O ni oun pinnu lati gba awọn owo naa ni ibamu ofinj ile wa.
Bakan naa la tun gbo pe igbakeji
aare lorile ede yii tun sagbekale awon igbimo pajawiri ti yoo maa ri si ounje
nibi tawon alakoso ajo NEMA, awon ologun ofurufu, oju omi ti jo n sise papo.Bee
lo ni awon igbimo naa sise po pelu tawon agbaye, O ni pelu alaye toun se yii o
fihan pe awon to ko ikokuko naa ko nise, won kan fi ailopolo won ba nnkan je.
No comments:
Post a Comment