Fun imurasile fun ipolongo ibo gomina ti
yoo bere ninu osu kejila odun yii, oludije gomina labe egbe oselu APC nipinle
Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti yan Omooba Segun Adesegun to ti figba kan je
igbakeji gomina nipinle naa gege bi alakoso agba fun ipolongo ibo gomina ti yoo
waye lodun to n bo.
Yiyan yii waye nibi ipade tegbe naa se
lojo Eti, Furaide, ana an, nile agba oselu egbe naa iyen Oloye Olusegun Osoba.
Onarebu Iziaq Abiodun Akinlade toun naa je oludije fun ipo gomina ni won fi se.
Lara awon igbimo olupolongo ibo gomina
fegbe naa tun ni Onarebu Bimbo Ashiru ti yoo je alakoso isuna owo ti won yoo lo
fun ipolongo nigba ti Omoona Tella yoo je igbakeji akoso ipolongo.
Onarebu Ganiu Hamzat ni yoo maa dari
Ogun Central, Onarebu Akande Omoniyi ni ti Ogun West nigba ti Arch Opayemi
Opabunmi yoo di Ogun East mu.
Awon ibi yooku ti won tun yan awon eeyan
si ni isakoso, ise akanse, atawon mi in ti gbogbo won so ti gba lati sise po
lati le rii pe Dapo Abiodun gbegba oroke nibi ibo gomina lodun to n bo yii.\
Nigba to n soro nibi agbekale awon
olupolongo naa, Omooba Dapo Abiodun tun mu da awon eeyan loju pe ijobba oun yoo
te siwaju nibi awon ise aseyori ti Gomina Ibikunle Amosun se boun ba le jawe
olubori fun ibo naa. O ni gbogbo ona to ba ye nijoba oun yoo sa lati rii pe
irorun deba awon araalu.
.
O wa lo akoko naa lati pe gbogbo
awon omo egbe osele APC nipinle Ogun lati jo wa ni isokan nitori agbajo owo la
fi n soya, ki gbogbo won le jo de ebute rere ninu egbe naa.
No comments:
Post a Comment