Ogbeni
Sunday Olaposi Oginni, to je akowe fegbe oselu Labour, nipinle Ogun, ti so pe
ko si adehun kankan laarin egbe naa pelu Gomina Ibikunle Amosun lati wa darapo
mo won.
O soro yii
lakooko to n ba awon oniroyin foro jomitoro oro leyin ti won pari ipade
pajawiri ti won se niluu Abeokuta. O so
pe ko si ooto ninu oro naa nitori ko sigba kankan tawon jo se ipade po depodepo
pe adehun wa laarin won.
Oginni wa
gba Seneto Ibikunle Amosun lamoran lati yera fawon to fee foruko egbe naa luu
ni jibit. O ni awon tawon je ojulowo omo egbe labour nipinle Ogun ko mo
nnkankan nipa e.
O wa salaye
pe gbogbo nnkan ti Arabambi Abayomi
Oluwafemi to n pe ara e ni alaga egbe naa sugbon tawon ti gbe e lo si
kootu ijoba apapo iyen Federal High Court to wa niluu Abeokuta pelu awon
isongbe e bii Sina Aroyeun ati Onarebu Ladi Adebutu ni asiri won yoo tu sita
laipe.
Oginni wa
pari oro e pe gbogbo erongba awon nile yii ati ni Oke- okun ni lati gba egbe
naa lowo awon oloselu onijekuje lawon yoo rii pe o seso rere nipa ti tele ona
titi de kootu to ga ju lo.
No comments:
Post a Comment