Igbimo to n ri si eto ipologo fun
oludije gomina labe egbe oselu APC nipinle Ogun , iyen Dapo Abiodun ti so pe ko
si ooto ninu iroyin kan ti won so pe o jade ninu iwe iroyin oloyinbo kan ti won
pe Sahara Reporter pe okunrin naa gbowo nla kan kale gege bi owo abetele fawon
oloye egbe naa lapapo ati alaga won, Adam Oshiomhole fun ti abajade ibo pamari
egbe naa. Won ni iro nla ni ati pe won fee fi tabuku oludije naa.
Gege bi atejade tegbe olupolongo naa
DACO fi sita ni won ti pariwo fawon araalu pe ki won maa gba gbogbo nnkan tiwe
iroyin naa gbe jade gbo, nitori ona lati fi dabaru nnkan ni.
Won ni ko sigba kankan ti Dapo
Abiodun fowo fa awon oloye egbe naa yala ni tipinle tabi ti apapo mora fun
gbogbo igba ti ibo pamari naa fi waye. Won pelu idaniloju lawon fi so pe
oludije won yii nigbagbo ninu agbekale ofin egbe pelu ilana ti won fi sile.
Egbe olupolongo naa wa so pe awon mo pe esun ti won fi kan
okunrin naa lowo awon eeyan ti won ko fee ki alafia joba nipinle Ogun ninu. Ati
pe gbogbo igba lawon gboriyin fun alaga
egbe naa lapapo lona to gba fi seto ibo abele naa lona ti ko mu wahala da ni
ati pe asaaju rere lokunrin naa.
Won wa gba gbogbo awon araalu
nimoran lati ma se feti si gbogbo ibaniloruje tabi ibaje ti won ba n se fun
Dapo Abiodun, nitori alara lara n ta. Won ni ariwo oja lasan ni, ko sooto
kankan nibe.
No comments:
Post a Comment