Oludije Aare egbe oselu KOWA bebe fun isokan. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 14 November 2018

Oludije Aare egbe oselu KOWA bebe fun isokan.

 
 
Oludije Aare fegbe oselu KOWA ninu ibo to n bo lodun 2019, Sina Fagbenro Byron ti so pe ipa Pataki ni idibo maa n ko ninu awon eeyan idi niyi to fi ni egbe oselu naa ti setan lati gba awonb omo orile ede yii kuro ninu ise ati iya, tawon to n se ijoba ko won si.
 
O wa bebe fun isokan ati ife laarin awon omo orile ede yii, ki won fi le dibo won fun egbe oselu KOWA ninu ibo naa kawon eto irorun le te won lowo.
 
 
O soro yii ninu atejade kan ti won fi sita, eyi ti SFB fowo si lo ti so pe  gbogbo ona lawon yoo fi satunto lori eto aje atawon nnkan mi in.
 
 
Oludije naa salaye pe egbe oselu KOWA n gbiyanju bi ajosepo yoo se wa lati pese isakoso to dara ni Naijiria ti iya pelu iponju awon eeyan yoo dopin.

O fi kun oro e awon omo orile ede yii ti setan lati fi ibo won le ijoba to wa lode jade nitori ti won kuna lati mu irorun ba igbe aye omoniyan

O ni bo tile je pe titi di akoko yii awon omo Naijiria ko tii dariji egbe oselu PDP nitori bi won se fi akoko sofo fun odun merindinlogun.

Sina tun so pe inu awon odo gan-an ko dun si bi nnkan se n lo lori bawon egbe oselu alatako se ati bi iwa ibaje se n gbile si laarin awon agba oselu.

Ọpọlọpọ eniyan ti ri kedere pe APC ni iṣoro pupọ lati pese agbara, idagbasoke ati itọsọna. Lati gbe Nigeria jade kuro ninu osi ati lati dẹkun iwa buruku..

Oludije naa so pe awon oludibo ko tii nigbagbo pe awon alatako egbe oselu ti setan lati gbakoso lowo ijoba to wa lode.

O wa muu dawon eeyan loju pe egbe KOWA ni egbe oselu to le gba ijoba lowo APC ninu ibo to n bo.


No comments:

Post a Comment

Pages