Oludije gomina labe
egbe oselu APC nipinle Eko,Ogbeni Babajide Sanwo- Olu ti mu Dokita Obafemi
Hamzat gege bi igbakeji e fun ibo gomina to n bo lodun 2019.
Nibi ipade oniroyin to
waye ni ofiisi egbe naa niluu Eko ni Sanwo- Olu ti safihan eni to fee fi se
igbakeji e yii fun Onarebu Tunde Balogun to je alaga egbe naa atawon oloye
yooku ninu egbe APC.
Nibe ni alaga egbe naa
nipinle Eko,Tunde Balogun ti so pe oun ni gbagbo pe eni ti oludije gomina ohun
mu yii ti je ko fihan pe awon to to se e ti won si le mu aseyori jade lawon
mejeeji naa.
Ninu oro tie, Sanwo-
Olu so pe boun se pinnu lati yan Hamzat gege bi igbakeji oun fun ibo gomina to
n bo mu ifokanbale wa foun pe ipinle Eko yoo tun se daadaa nitori iru eeyan ti
eni toun mu naa je.
O tun salaye pe odu lawon mejeeji ki i se aimo foloko ninu
awon agbo oselu, awon si ti n ba ara won bo o tile ni ogun odun, bawon se je
ore bee lawon tun je tegbon taburo pelu.
O tun sapejuwe e gege
bi eni toun nigbagbo ninu e awon le jo sise po to le ran ijoba oun lowo lati
gbe ipinle Eko goke agba ju bo ti wa tele lo.
Nigba toun naa soro pe oun gba lati baa sise po, Hamzat so pe
oun ati Sanwo- Olu mo nnkan tawon le se fun ipinle Eko to le mu nnkan rorun fun
won.
O loun gba lati se igbakeji e pelu idaniloju pe egbe oselu APC
ni yoo jawe olubori nibi gbogbo ibo to n bo lodun to n bo pelu ileri pe oun ko
nii dale oga oun nigba tawon ba bere si nii sise po.
No comments:
Post a Comment