Niyi Osoba gba tiketi asoju-sofin fun ekun aarin gungun Ijebu fegbe oselu Labour. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 27 October 2018

Niyi Osoba gba tiketi asoju-sofin fun ekun aarin gungun Ijebu fegbe oselu Labour.



Dokita Niyi Osoba legbe oselu Labour ti fun un ni tiketi lati soju won gege asoju-sofin fun ekun aarin gungun Ijebu iyen Ijebu Constituency ninu ibo to n lodun 2019.

Gege bi atejade to te wa lowo, okunrin yii to ti figba kan je alaga fegbe awon osise iyen Labour nipinle Ogun ni yoo koju awon yooku latinu egbe oselu mii in lati dije fun ipo naa.

Bo tile je pe odu ni Oloye Niyi Osoba lagbo oselu ki i saimo foloko, bo ti se sise ijoba to feyinti bee naa lo ti di awon ipo gidi mu ninu oselu.

Osoba ti figba kan ke oluranlowo fun Gomina Gbenga Daniel lakooko tiyen fi n se ijoba, bee naa lo je pe oun ni won fi se alaga fegbe oselu Labour nipinle Ogun, ko to di pe won pada sinu egbe oselu PDP.

Bakan naa ni Giwa tun ti je alakoso agbenuso fegbe oselu PDP yii opo ipo mii in lo tun ti di mu. Ko to di pe egbe oselu Labour fun ni tiketi asoju-soju niluu Abuja nibi ibo odun 2019.

Oludije naa ti wa seleri pe oun ko nii doju tawon eeyan e bi won ba fi le fibo gbe oun wole ati pe opo awon nnkan toun mo pe o je awon eeyan agbegbe e logun loun yoo rii pe oun yoo se, nitori egbe ti ki I feto dun araalu legbe labour.


No comments:

Post a Comment

Pages