Asiko ta a wa yii ki i
se akoko to dara fun Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun nitori bo se n ba
ijakule pade latigba ti won ti seto ibo ipade gbo-gbo-gbo egbe naa lori eni to
fee ko se gomina leyin oun, iyen Abdulkabir Akinlade.
Iwadi fi ye wa pe
gbogbo igbese ti okunrin Gomina naa n gbe boya o le bori awon ti won jo n fa
oro naa ni ko seso rere to si je pe titi di akoko yii se ni Amosun si ko agidi
bori.
Ohun kan to si n jade
lenu e ni pe Akinlade toun fowo sii ni yoo je oludije fegbe oselu APC ki i se
Dapo Abiodun ti igbimo ti won yan lati seto ibo naa iyen NWC daruko ni yoo
dije.
Bo tile je pe latigba
ti wahala naa ti bere la gbo pe okunrin naa ko ti ni isinmi mo, o fee je pe
Abuja lo n gbe ju amo gbogbo irinajo to n rin naa ko I tii si eyi to so eso
rere.
Bi a ba si ni ka woo,
yoo ti to eemeta otooto ti okunrin naa ti se ipade po pelu Aare Mohammadu
Buhari ti won lo fee lo ore ofe pe oun ati okunrin naa sunmo ara won.
Bakan naa lo se je pe lojo Aiku,Sannde,to koja
yii ni okunrin ohun tun ko awon oba laye meji, Oba Adedotun Aremu, Alake tile
Egba ati Oba Kehinde Olugbenle,ati Seneto Iyabo Anisulowo loo sodo Aare Buhari,
ko si si nnkan mii in bikose oro pe dandan Akinlade toun mu naa ni ki won boun
fowo si gege bi oludije.
Sugbon bi igba ti
okunrin naa n fakoko re sofo loro ri, nitori awon alase egbe ko setan lati yi
ipinnu won pada, Dapo Abiodun ni won fowo si pe oun lo jawe olubori nibi ibo ti
won seto e naa.
Nigba ti Amosun tun de
lati Abuja lojo Aje, Monde, ose yii bombu lo tun ju ranse sawon agba egbe kan
ninu egbe oselu APC,awon naa ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Oloye Segun Osoba
ati Adams Osiohmole to je alaga egbe naa lapapo, o fesun jibiti kan awon eeyan
naa lori ibo egbe naa to waye nipinle Ogun.
O ni awon eeyan naa ko
soro lori wahala to n waye nipinle naa, eyi to tumo si pe won fowo Dapo
Abiodun, ti ko si ye ko ri bee,a fi bo se di ana an, ojoruu, Weside, ti Mallam
Lanre Isa- Onilu to je alukoro fegbe oselu APC lapapo foko oro ranse si Amosun,
nibi to ti yeye e, to ni alada nikan se eeyan ni to si se afojudi egbe pe kin
ni won fee se.
O so pe latigba ti
imurasile eto naa ti bere ni Amosun ti so ara e di Olorun lori awon eeyan, ti
ko si fi tegbe se, gbogbo nnkan toun naa mo pe ko tona, lo se to si roo pe oun
ni agbara ju egbe lo.
O ni Aare Mohammadu to
lo n sa ba nitori pe won sunmo ara won naa mo pe pataki ni egbe, ati pe gbogbo
nnkan to n so naa ni aare naa n beeere nipase ona ofin, o ni ko si ipada seyin
mo, ete lo ba de Amosun, nitori Dapo Abiodun to wole lawon wa leyin e.
No comments:
Post a Comment