Omooba- binrin
Abiodun Oyefusi to je oludije fun ipo seneto ni ekun Lagos East labe egbe oselu
PDP ti so pe o da oun loju pe obinrin si le se ju awon okunrin lo ninu oselu ti
won ba le fun won laaye.
Obinrin naa soro
yii lakooko to n ba awon oniroyin soro niluu Eko lori erongba e lati dije fun
ipo omo ile igbimo asofin niluu Abuja iyen seneto ninu ibo gbogbogboo ti yoo
waye lodun 2019.
O so pe bawon
obinrin naa se n jade lati dupo fawon to se koko ninu oselu je nnkan to wu ni
lori eyi to ti n yato si ti tele,o ni pelu boro se ri yii I fihan gbangba pe
awon obinrin naa ko fee maa fee fa seyin mo.
Bakan naa lo tun
ro awon oludibo lati ma se dibo nitori pe boya o je okunrin lo dije bi ko se pe
ki won dibo feni ti won mo pe to le se daadaa ko baa je obinrin.
O so pe ojoojumo
loju maa n la si bayii, o si ye kawon oludibo mo nnkan ti koja bii ti tele nidi
oselu, nitori opo nnkan tokunrin ko le se nidii oselu lobinrin le se ju bee lo
ti yoo si mu iderun bara ilu.
|O ni edun okan lo je pe obinrin ko tii depo
gomina ati aare lorileede n yii sugbon idaniloju wa pe obinrin si maa debe. O
ni awon obinrin ni nnkan ti won le se lati le mu ki itesiwaju ba
orileede.Nitori laarin awon eni to le se gomina tabi aare ti yoo mu ilu dun wa
ninu iyen ti won ba faye gba awon.
Abiodun Oyefusi
tun salaye siwaju pe titi di akoko ti a n soro yii, eni to n dari oro aje to
daa ju lagbaye obinrin lo n dari e.
Nigba to n menuba
nnkan to mu ifaseyin bawon obirin ti won ki I fi ni asoju pupo nidi oselu,
oludije naa so pe lodun 2018 ida ogota lawon to si je pe awon ki I kopa ninu
oselu sugbon ni bayii, ida marundinlogoji lawon fee, ki won kopa, ki won si ro
won lagbara.
Nigba to n so
nnkan to ni lokan fawon eeyan e, Omooba- binrin naa so pe oun setan lati je ku
nnkan rorun fawon eeyan ibe, o ni ko nii je isoro foun nitori aarin won bi oun
si toun si tun dagba si. Ati pe gbogbo nnkan ti won ba fee ni yoo maa te won
lowo lakooko.
No comments:
Post a Comment