Ogbeni Yinka Dada,
okan lara awon olugbe Imogun, nipinle Ekiti ti sapejuwe ibura ti won se fun
Gomina Kayode Fayemi, gomina tuntun nipinle naa gege bii ibura fawon ole
oloselu lati fun fi ko awon eeyan sinu igbekun leekan si.
Ninu atejade ti
okunrin naa fi sita, eyi to te wa lowo fi ye wa pe ibura to waye naa ki I se
nnkan to dun mo gbogbo awon araalu ninu, nitori ibo ti won fi gbe e wole lojo kerinla osu keje lo je eyi to mu ojooro
ninu ipamopo egbe oselu APC ati ajo eleto idibo iyen INEC ni won jo sise naa.
O so pe gege bi okan
lara araalu, ibo to waye nigba naa tawon APC sajoyo pe won wole yii lo kun fun
pe won ra ibo, bee ni won tun gbe esi ti ko fese rinle jade, eyi to da oun loju
pe igbejo to n lo lowo nipa yoo danu laipe.
Yinka Dada tun so pe
bi won se se ibura fun ijoba Fayemi lati gbakoso ipinle Ekiti je ko ye awon
araalu pe ipadabo awon ole oloselu, ti ko tinu ife awon eeyan wa ti won wa lati
jogun nnkan ti won ko sise fun ni.
O ni pelu esun ti won
fi kan lori ibo to waye naa, nibi ti egberun lona irinwo ti dibo, ti Kayode
Fayemi ti jawe olubori pelu esi ibo to mu iyanu wa, nipa isiro tawon ajo INEC
gbe jade.
Ibanuje okan lo je pe
pelu bi ibo naa se lo ni irowo rese, ti ko si wahala to wa je pe esi ibo ti won
gbe jade lo ba nnkan je pupo.O ni bo tile je pe fun odidi odun merin ti Fayose
fi se gomina lo fi se ijoba okoowo nibi to ti ko awon araalu sabe e.
Yinka ni ko si nnkan
tuntun ti Fayose mu ba ijoba e laarin odun merin naa bee lo ni o so ara e di
alawada, gbogbo awon to ye ko ko mora lo fimo tara eni le danu, eyi to so pe o
mu kawon APC gba awon yen gege bi omo oninakuna.
Okunrin yii wa gba
onidajo Belgore to n gbejo idibo naa lati se lona to to ati eyi to ye ko ma se
je kawon to fole oselu ja awon araalu ba ijoba tiwantiwa yii je.O ni awon
araalu fee mo idi ti esi ibo ti swon gbe jade ko ba nnkan to wa nile mu.O ni ko
fidi idajo ododo mule. O so pe o da oun loju pe awon eeyan ipinle Ekiti yoo gba
eto won pada.
No comments:
Post a Comment