Bi eto idibo se ku die ko waye lodun
to n bo, Dokita Bolaji Akinyemi, to je alakoso patapata fegbe akanse ipe isegun
iyen Project Victory Call [PVC] lorileede yii, ti ke sawon odo lati wa ni
igbaradi lona ti won yoo fi ba awujo figagbaga lori oro oselu.
Okunrin yii soro naa lakooko to n ba
awon oniroyin soro lori ayajo awon akekoo lagbaye nibi to ti se idanilekoo lori
oro kan ti akori e je eko nipa oselu, ifigagbaga pelu awujo lagbaye.Eyi to waye
lojo Aje, Monde, ose yii ni gbongan LCCI, Alausa, Ikeja, niluu Eko.
O so pe akoko ti to fawon odo lati gba
ara won sile lowo oselu to mu etanu da ni ati pe ki won maa je ki won maa lo
won nilokulo.
O tun so ninu idanilekoo e pe eto
eko je nnkan amulo, kokoro to n nipa si idagbasoke omo eeyan bee lo salaye pe
ipa ti eto eko n ko, ko se e fowo ro seyin, eni ti ko ni I bigba tonitohun wa
ninu osi ni.
Dokita Akinyemi tun salaye pe bi a
ba fee gba orileede yii sile fun ibo odun 2019, a gbodo gbe awon igbese ti yoo
kese jari lati da awon araalu lekoo, ki a si lawon loye lona ti won yoo fi dibo
naa sona to to ati eyi to ye.
Bakan naa lo so pe awon odo nikan lo
le gba awon obi won lowo ewu nipase eto eko to nii se pelu oselu.O ni bawon
eeyan ko ba mo eko oselu lo je gege bii idanimo fojo iwaju, bi yoo si se ri ni
ola, imurasile re gbodo ti bere loni in.
Akinyemi tun so pe’ Bi a ba ni ka
woo, gbogbo orileede agbaye ni won figagbaga lati mu nnkan gidi jade sugbon
tawon asaaju n mu ifaseyin ,ki i se oro enu, opo awon orileede ni won ti fi wa
sile nipa eto oselu, to je pe se la n to won leyin’.
O ni pataki nnkan to je PVC – Naija
lokan bayii lati fojunu wo ere ije tawon gbodo sa fun ti ibo to n bo lodun
2019. Bee lo salaye pe bi a ba ni ka wo ikaniyan wa lorileede yii, a ti fee to
milionu lona aadojo si igba.O ni eyi to je isoro ta o le samojuto nitori bi a
se po si.
Akinyemi ni a gbodo gbe igbese lati
se ipinnu to ye fodun 2019, nitori eni to pe omo odun mejidinlogun lodun yii,
nigba ti yoo ba fi di odun 2050 yoo tip e aadota odun, ati pe ajo agbaye ti so
pe nigba ti yoo ba fi pe odun naa,orileede yii ni yoo wa nipo keta awon to po
ju lo lagbaye.
O wa sagbekale e pe 2019 ni awon odo
gbodo bere igbese pelu igboya pe won gbodo depo aare laarin 2019-2023 gege bi
igbese akoko, igbese keji laarin 2027-2035 ati igbese keta 2035-2043 ati igbese
to pari 2043-2051 fun ipo aare.
O niegbe PCV- Naija wa ke si gbogbo
awon odo lati dide fun ayipada rere lati lo awon egbe oselu titi de 2050.
No comments:
Post a Comment