Bi oludije gomina
ipinle labe egbe oselu APC ninu ibo to n bo lodun 2019, Ogbeni Babajide
Sanwo-Olu se mu Dokita Obafemi Hamzat gege bi igbakeji e lati le jo sise po la
gbo pe won ni yoo tubo mu idagbasoke ba ipinle Eko bi won ba gba akoso.
Ninu
atejade kan ti Ogbeni Kunle Sijuade to je alabojuto fegbe awon akoroyin
Sanwo-Olu fun ipo gomina fowo si lo ti so pe awon mejeeji naa yoo lo awon iriri
won ti won ti ni nipa oselu lati fi ki ipinle naa tun te siwaju ninu ohun
gbogbo.
O tun salaye pe Onarebu Hamzat yoo lo ogbon pelu
iriri e lati fi sise po pelu oga e yii bee ni won tun gboriyin fawon asaaju
egbe naa nitori bi won se fowosi ki Sanwo- Olu ati Hamzat jo sejoba papo ninu
ibo to n bo naa.
Kunle tun so siwaju pe o dawon loju
pe oludije gomina labe egbe oselu APC yii yoo se daadaa ju bawon eeyan se ro
tele nitori iriri e lawujo atawon to ti baa sise po. O ni idunnu lo je pe egbe
oselu APC nipinle Eko gbero nnkan gidi
fawon araalu nipa bi won se gba kawon mejeeji naa sise po.
Bee ni won wa gboriyin fun Asiwaju
Bola Ahmed Tinubu fun ipa ribiribi to ti n ko ninu oselu lati odun 1999. Bakan
naa ni won gba awon araalu nimoran lati jade dibo won fun APC ninu ibo odun to
n bo, ki gbogbo won le tubo maa je mudunmudun ijoba tiwantiwa.
No comments:
Post a Comment