Egbe oselu PDP ti Ogun West ti dibo
yan Onarebu Leye Odunjo gege bii oludije won fun ipo seneto iyen omo ile igbimo
asofin niluu Abuja nibi ibo to n bo lodun 2009. Nibi eto naa to waye niluu
Ilaro lojo Isegun, Tusidee, lawon asoju ti won le ni eedegbeta ti dibo fun
okunrin naa pe oun lawon yan lati koju egbe oselu mi in.
Onarebu Koye Ijaduoye atawon meji mi
in ni won yan lati wa seto naa. Bee la gbo pe awon ijoba ibile maraarun ti won
wa labe Ogun West ni won ran asoju wa sibe, awon ijoba ibile naa ni
Imeko,Ipokia, Yewa South, Yewa North ati Ado- Odo Ota.
Ninu oro e leyin ti won dibo yan an
tan, Onarebu Leye Odunjo dupe lowo awon eeyan e fun agbekele ti won ni ninu e,
ti won fi dibo fun un lati loo dije labe egbe oselu naa, o ni inu oun dun gidi
pelu ileri pe oun ko nii ja won nitanmo.
Bakan naa lo so pe bi ibo naa se waye
laisi wahala ati ija kankan tun je kawon eeyan mo pe inu isokan lawon n gbe
ninu egbe oselu PDP. O wa seleri pe gbogbo awon nnkan to ba ye lati gba jade
lowo ijoba to je eto awon eeyan e loun yoo rii pe oun gba bi oun ba le wole
ninu ibo naa lodun to n bo.
Bee lo so pe ko si nnkan to je pe PDP
pin meji pelu awuyewuye to n lo nigboro, o ni okan ni egbe naa nipinle Ogun, ko si si eleyameya rara. O
ni egbe naa si ti setan lati le ijoba APC to wa lode yii lo patapata, nitori
araalu ko nii gbekele ninu won mo.
.
No comments:
Post a Comment