Ibo pamari gomina APC nipinle Ogun, Ibon ni won fi n le ara won kaakiri - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 2 October 2018

Ibo pamari gomina APC nipinle Ogun, Ibon ni won fi n le ara won kaakiri





Bi eeyan ba so pe ibo pamari gomina tegbe oselu APC nipinle Ogun loo bo ti to ati bo ti ye iro to jinna sooto ni, nitori bawon toogi inu egbe naa se ko ibon jade ti won si n daa bo le, ki eto idibo naa ma baa lo nirowo rese.
Lati ale ojo Aje, Monde, ni wahala naa ti bere lakooko tawon ti won yan lati samojuto idibo naa se ipade po pelu awon oludije, ti won fee kopa nibi ibo naa
Sugbon se loro naa di bo-o- lo- ya fun- mi nigba ti iro ibon n dun lakolako lawon agbegbe naa, opo awon to si wa nibe ni won n sa fun emi ara won.
Kekere ni eleyii, pabanbari e lo waye lojo Tusidee to ye ki ibo waye nitori se lawon iro ibon yii tun dun lawon agbegbe kan niluu Abeokuta. Pelu nnkan to n sele yii, lo je kawon kan so pe o seese ki won sun ibo naa sojo iwaju.
Oro yii lo n ja nile, ti alukoro egbe naa, Wole Elegbede fi gbe atejade kan sita pe won yoo dibo lojo naa, amo gbogbo ibi ti oniroyin wa de, la gbo pe inu fu, aya fu lawon to fee dibo naa fi wa lawon ibudo ti won ti fee dii.
Nigba ti yoo fi di owo osan  niroyin fi to wa leti pe ilu Ifo ti daru, won lawon toogi n yin ibon kaakiri bere lati Abe- Koko,bee ni won tun ba opo nnkan je, nigba tawon kan sii farapa yannayanna.
Titi di akoko yii ko seni to le so pe bayii ni ibo pamari naa yoo yori si, ohun tawon kan n so ninu egbe naa nip e awon omo eyin Gomina Amosun lo ko ibon wole, nitori ki oludije won lee wole. Sugbon tawon ti Amosun naa so pe awon ti Dapo Abiodun ni.
Ohun tawon araalu wa n so nip e nigba ti ibo gbogbogboo ko tii waye tawon omo egbe APC n se bayii laarin ara won, kin ni won wa fee se lodun 2019 ti ibo yoo waye.



No comments:

Post a Comment

Pages