Alaga fegbe
oselu ADC nipinle Eko, Oloye Babatunde Daramola ti so pe ibanuje okan lo je pe
bi orileede wa se sayeye ayajo odun mejidinlogota to gba ominira, a ko tii
bawon yooku ta jo gba nigba kan naa ninu idagbasoke. Ati pe a ko tii de ibi to
ye gege bi eni to ti gba ominira.
O soro yii
lakooko to n bawon oniroyin soro nipa ayajo ominira orileede, eyi tegbe oselu
naa se ni ara oto.
O so pe o ti
ye ki ile Naijiria ti goke ju bayii lo sugbon tawon adari to n dari latile
atawon to wa nibe ti ba nnkan je jinna.
O ni itiju
nla lo si je pea won taa saaju won gba ominira ti goke ju wa lo, ayafi ti
gbogbo wa ba le ja fitafita la ti le awon obayeje naa lo.
Bakan naa lo
so pe bi Gomina Akinwumi Ambode ba so pe oun fee darapo mo egbe won, awon setan
lati gba a wole, sugbon ki i se pea won yoo fun ni tiketi loju ese nitori awon
ti lawon oludije nile tele.
Alaga ADP
naa tun so pe gbogbo nnkan to n sele ninu egbe APC ipinle Eko ti je ka mo pe
awon kan wa ti won ti so ara won di kokoro ile egbe, to je pe bo ba wu won, won
le si, bo ba si wu won won leti pada. O ni irinajo tegbe oselu naa n hu lati
bii odun mokandinlogun seyin.
O so pe awon
marun un kan ni won da egbe oselu APC ipinle ru, o ni oun ko fee daruko won
bayii, o ni owo won ni ase egbe naa wa, awon eeyan wonyii lo si ti so ara won
di eru jeje.
Ko to to akoko
naa, ni alaga egbe naa ni orileede yii ti saaju awon omo egbe se ipolongo nipa
bi boa won eeyan lowo fayeye ajodun ominira naa.
No comments:
Post a Comment